Ẹ wo ile-ẹkọ 'Kwara Smart' t'ijọba ṣẹṣẹ pari bo ṣe rẹwa to - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 18, 2022

Ẹ wo ile-ẹkọ 'Kwara Smart' t'ijọba ṣẹṣẹ pari bo ṣe rẹwa to


Idagbasoke nla ara-ọtọ leyi tun jẹ lẹka eto ẹkọ n'ipinlẹ Kwara pẹlu bi ijọba ipinlẹ naa tun ṣe kede sita wi pe iṣẹ ti pari nile ẹkọ igbalode tuntun ti wọn pe ni Kwara Smart Model College to wa lagbegbe Adeta, ilu Ilọrin.
 
Lara awọn iṣẹ akanṣe ti ajọ UBEC, iyẹn Universal Basic Education Commission n'ipinlẹ naa dawọ le, eyi ti ijọba Kwara ṣagbatẹru rẹ ni ile ẹkọ Kwara Smart Model School jẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
A gbọ pe ọdun meje gbako ni ajọ UBEC fi yọ orukọ ipinlẹ Kwara kuro ninu awọn ipinlẹ ti wọn yoo maa da si eto ẹkọ wọn, eyi to mu ki ijọba ipinlẹ naa tun tọwọ bọ iwe adehun tuntun pẹlu ajọ naa, lati le jẹ ki eto ẹkọ tubọ kẹsẹjari.
 
Nipasẹ iranwọ owo ti ajọ UBEC gbe kalẹ la gbọ pe wọn fi tete pari ile-ẹkọ naa.
 
AWIKONKO gbọ pe ile-ẹkọ ti ko din ni ẹgbẹta ninu ẹgbẹrun le ni irinwo, 1400 ni wọn ti gba atunṣe latigba ti Gomina AbdulRazaq ti gba ijọba lọdun 2019.
 
Ile-ẹkọ tuntun yii lo tun fi apẹẹrẹ rere lelẹ wi pe idagbasoke alailẹgbẹ lo n de ba eto ẹkọ n'ipinlẹ naa.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI