Ayẹyẹ Ọdún Kan: AbdulRazaq bá Olúpò t'ìlú Àjàṣẹ́-Ìpó yọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 23, 2022

Ayẹyẹ Ọdún Kan: AbdulRazaq bá Olúpò t'ìlú Àjàṣẹ́-Ìpó yọ̀


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ba Ọba Ismail Yahaya Alebioṣu, Olupo ti ilu Ajaṣẹ-Ipo yọ lori ayẹyẹ ọdun kan to pe lori ipo awọn baba-nla rẹ to si gba a ladura wi pe irukẹrẹ yoo di anẹrẹ mọ kabiyesi lọwọ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita laipẹ yii, lati fi ki Kabiyesi, lo ti jẹ ko di mimọ pe oun nífẹẹ ai iru eeyan ti Ọba naa je gẹgẹ bi oniwa tutu to tun n fẹ idagbasoke agbegbe rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI