Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ninu erongba ohun lati jẹ ki iṣoro omi ẹrọ to ja geere di ohun igbagbe kaakiri ipinlẹ naa, awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣe omi ẹrọ igbalode ti ko din ni mejidinlaadọta fawọn araalu.
Miliọnu lọna aadọjọ naira (₦150,000,000) naira ni ijọba Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lohun ti ya silẹ lati ṣe omi ẹrọ igbalode, iyẹn Motorized Boreholes kaakiri ijọba ibilẹ Moro ati Asa.
O ni pẹlu awọn agba ti wọn yoo maa pọn omi si, ti awọn araalu ko si ni maa daamu lati wa omi ti wọn yoo lo lati fi ṣe ohun to ba wu wọn.
Eyii la gbọ pe o tun wu ìjọba apapọ lori ti wọn fi l'awọn yoo ṣe omi ẹrọ igbalode ti yoo maa ba oorun ṣiṣẹ, eyi ti ko ni jẹ k'awọn araalu duro de igba ti ina mọnamọna ba de, ko to di pe wọn ri omi lo.
Ijọba ibilẹ Edu ati Ọffa la gbọ pe wọn fẹẹ ṣe awọn omi naa ti ko din ni ogun si, fun irọrun araalu.
Kọmiṣanna f'ọrọ eto iṣuna, Ọnarebu Florence Ọlasumbọ Oyeyẹmi lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Babatunde Toyin Abdulrasheed fi sita.
No comments:
Post a Comment