Awọn agbebọn tun kọlu awọn arinrin-ajo mẹrin l'Ọṣun, diẹ lo ku ki wọn ji wọn gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 14, 2022

Awọn agbebọn tun kọlu awọn arinrin-ajo mẹrin l'Ọṣun, diẹ lo ku ki wọn ji wọn gbe


Bi ki i ba a ṣe ori to ko awọn arinrin-ajo mẹrin kan ti a fi orukọ bo laṣiri yọ lọwọ awọn agbebọn ni, boya ohun ti a n kọ yii kọ lao ba maa kọ, ṣugbọn ti wọn n pada dupẹ lọwọ ẹlẹda wọn bayii.
 
Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka t'ipinlẹ Ọṣun ti f'idi rẹ mulẹ wi pe ori ti kọ awọn arinrin-ajo mẹrin kan yọ lọwọ ikọlu awọn agbebọn ti wọn da wọn lọna pẹlu ibọn loju ọna atijọ ti Ila Ọrangun si Ijabe, ipinlẹ naa.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, a gbọ pe ṣe lawọn agbebọn naa dena de awọn arinrin-ajo yii pẹlu ibọn at'awọn nnkan ija oloro.
 
Wọn ni b'awọn agbebọn naa ṣe kọlu awọn arinrin-ajọ ni wọn ti ranṣẹ s'awọn oṣiṣẹ eleto aabo Amọtẹkun, t'awọn yẹn si sare debẹ lati ṣe iranwọ fun wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe owọ pada tẹ ọkan lara awọn agbebọn naa, nigba ti awọn yooku rẹ raaye na papa bora.
 
Wọn l'awọn arinrin-ajo mẹrẹẹrin yii ni wọn farapa yannayanna.
 
N'igba to n f'idi rẹ mulẹ, Amitolu Shittu, to jẹ adari ileeṣẹ naa sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ọkan lara awọn agbebọn tọwọ tẹ, ati pe awọn to farapa ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI