Ẹmir tiluu Ilesha Baruba, ijọba ibilẹ Baruten, n'ipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Halidu Abubakar ti sọ ọ nita gbangba wi pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe ọpọlọpọ bẹbẹ nipa iṣẹ akanṣe idagbasoke, to si l'awọn ṣetan lati gbaruku ti bi yoo ṣe pada s'ipo naa lẹẹkeji.
Ọjọgbọn Abubakar ni ọpọlọpọ anfaani ni ilu Ilesha Baruba ti jẹ labẹ iṣakoso Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, to si ni awọn yoo maa dupẹ lọwọ ẹni to mu ọlaju wa fun wọn.
Bakan naa lo sọ pe ipa ti gomina ko niluu wọn yii, lo jẹ ki wọn ronu lati sọ orukọ ọna Ringroad to wa lagbegbe naa, lorukọ Gomina AbdulRazaq, pẹlu bi wọn ṣe pari ipele akọkọ lori opopona ti wọn n ṣe lọwọ yii.
Lakoko
to n sọrọ nibi abẹwo ti Gomina AbdulRazaq ṣe lọ sibi ti iṣẹ akanṣe
opopona naa ti n lọ lọwọ, Ọjọgbọn Abubakar sọ pe ọpọlọpọ nnkan lo ti
yipada nipasẹ opopona to ja geere t'ijọba ṣe f'awọn, eyi to lo tun mu ki
eto ọrọ aje agbegbe naa dagbasoke.
O
jẹ ko di mimọ pe aarin oṣu mẹta pere ni wọn fi bẹrẹ ọna ọhun, to si ti
fẹẹ pari, eyi to lo ti di dandan lati gbaruku ti saa keji fun un.
No comments:
Post a Comment