Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu Hassan Azeez Elewu, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Oluwanilo gẹgẹ bi amugbalẹgbẹẹ pataki lori ọrọ ofin, iyẹn Legislative Matters.
Hassan Elewu, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa la gbọ pe o ti figba kan ri jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, to si tun jẹ oniṣowo nla.
Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (Ilorin South) ni wọn pe Oluwanilo, to kẹkọọ gboye NCE nile ẹkọ Kwara State College of Education to qa niluu Ilọrin.
Rafiu Ajakaye to jẹ akọwe iroyin gomina jẹ ko ye wa pe alẹnulọrọ loun naa jẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lagbegbe rẹ.
No comments:
Post a Comment