Peter f’ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, ó tún lóun kò du ipò ààrẹ mọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 25, 2022

Peter f’ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, ó tún lóun kò du ipò ààrẹ mọ́


Gomina tẹlẹri n’ipinlẹ Anambra, ẹni to n gbero lati jade du ipo Aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Peter Obi ti kọwe f’ẹgbẹ oṣelu naa silẹ, bẹẹ lo si tun loun ko du ipo aarẹ mọ.

Peter Obi lo sọ eyi di mimọ ninu lẹta kan to fi ranṣẹ s’awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP, paapaa alaga ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Iyorchia Ayu l’ọjọ Ẹti, Furaide ọsẹ to kọja yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii.

Lẹta ọhun to pe akọle rẹ ni ‘Kikọwe f’ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party and yiyọwọ kuro lati jade du ipo aarẹ’, iyẹn Resignation From Peoples Democratic and Withdrawal From the Presidential Contest, Obi ṣalaye pe iduunu nla lo jẹ f’oun lati mu idagbasoke ba orileede yii nipaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP

Ninu lẹta naa, o sọ pe “Mo n kọ iwe yii lati fi ikọwe f’ipo mi silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, eyi ti mo ti fi ranṣẹ si alaga wọọdu Agulu keji, ijọba ibilẹ Anaocha, Anambra, bẹrẹ lati ọjọ Eti, Furaide, ogunjọ, oṣu karun-un, ọdun 2022.

“Siwaju si i, mo tun fẹẹ fi lẹta yii sọ fun un yin pe mo ti yọwọ mi kuro ninu a n du ipo aarẹ ati idibo abẹle.

“Anfaani nla lo jẹ wi pe mo ti kopa ninu idagbasoke orileede yii nipasẹ ẹgbẹ oṣelu wa. O ṣeni laanu, awọn iṣẹlẹ to n waye ninu ẹgbẹ wa lẹnu ọjọ mẹta yii, ko fẹẹ le jẹ ki n tẹsiwaju mọ.”

Lẹta naa ree



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI