Bo tun ṣe ri anfaani gba lati jade du ipo gomina lẹẹkeji labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti dupẹ gidigidi lọwọ awọn ọmọ ati olugbe, paapaa awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ naa, lori bo ṣe tun jẹ ọmọ oye fun ipo gomina lẹgbẹ ọhun.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC n'ipinlẹ Kwara dibo yan lati pada s'ipo naa lẹẹkeji, pẹlu erongba lati pari awọn akanṣe iṣẹ to n ṣe lọwọ.
Nigba to dupẹ lọwọ awọn araalu, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn lẹyin to jawe olubori nibi idibo abẹnu ẹgbẹ naa to waye lọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ yii, AbdulRazaq sọ pe inu oun dun gidigidi wi pe awọn araalu ni igbagbọ ninu oun pupọ.
"Ọpẹ mi lọ sọdọ gbogbo awọn oludibo ẹgbẹ, ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara fun ọwọ nla ti wọn fun mi. Mo tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọba wa, awọn adari, awọn ọmọ ẹgbẹ, at'awọn agbaagba kaakiri ipinlẹ Kwara. Mi o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu igbaruku ti yin."
Siwaju si i lo tun jẹ ko di mimọ pe laaarin 2019 si asiko yii, gbogbo ajalu ati ibanijẹ Kwara ti yipada, ati pe ko si agbegbe tabi igberiko kan ti awọn eeyan ko ti ni imọlara ijọba rere, nitori pe ayanmọ ipinlẹ naa ko si lọwọ ẹni kankan mọ.
No comments:
Post a Comment