Lọjọ ọdun Itunu Aawẹ: Ero rẹpẹtẹ lẹyin Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 3, 2022

Lọjọ ọdun Itunu Aawẹ: Ero rẹpẹtẹ lẹyin Gomina AbdulRazaq


Lara awọn ọjọ manigbagbe lọjọ Aje, Mọnde ana yii jẹ kaakiri ipinlẹ Kwara, paapaa niluu Ilọrin to jẹ olu-ilu ipinlẹ naa, nitori pe itan tuntun ni wọn tun fi balẹ lori b'awọn agbaagba, ọtọkulu ṣe wọ ilẹ adura awọn musulumi lati kirun. 
 
Pẹlu idunnu ati ayọ la gbọ pe awọn araalu, paapaa awọn musulumi fi lọ kirun ni Yidi agba to wa niluu Ilọrin lati kopa ninu irun kiki ti ipari aawẹ Ramadaani to ṣẹṣẹ kọja yii.

Ẹsẹ ko gbero rara, pẹlu b'awọn araalu, awọn alẹnulọrọ, aṣofin, aṣoju-ṣofin, Ọba alaye ṣe lọ darapọ mọ awọn ọmọlẹyin Allah yọ lati kirun ọdun.
 
Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti pinlẹ naa ko gbẹyin nibi irun kiki yii, koda ti Ẹmir tiluu Ilọrun, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, ti awọn ọba alaye kọwọrin pẹlu ẹ naa ko gbẹyin.

Imaamu Agba nni niluu Ilọrin, Sheikh Muhammad Bashir la gbọ pe o lewaju adura irun kiki nibi t'awọn ẹgbẹẹgbẹrun Musulumi ti peju pesẹ.
 
Diẹ ree lara awọn fọto bi nnkan ṣe lọ.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI