Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti gbe igbimọ alagbeyẹwo iwadii, ẹlẹni mẹfa dide lori ohun to n fa wahala nile ẹkọ girama ti Oyun Baptist High School to wa ni Ijagbo, iyẹn lori ọrọ Ijaabu.
Igbimọ naa la gbọ pe yoo ṣe agbeyẹwo ati awọn amọran lori iwadii ijinlẹ finnifinni ti igbimọ oluwadi ti wọn yan ṣaaju ti ṣe lori ọrọ wahala Ijaabu.
Ọjọgbọn l'ẹka ofin, Amofin Amuda Kannike SAN ni alaga igbimọ ọhun, nigba ti Ọgbẹni Amos Thompson jẹ akọwe igbimọ naa. Awọn yooku ti wọn jẹ ọmọ igbimọ ni: Amofin Joseph Sunday Bamigboye SAN; Ọmọwe Haruna Baba Gogata; Arabinrin F.O. Titiloye ati Ọmọwe Saadat Yetunde Yusuf.
Siwaju si i, igbimọ yii la gbọ pe wọn yoo ṣe agbeyẹwo awọn iwadii ti igbimọ oluwadii ti ṣe ṣaaju lori ohun to n fa wahala laaarin awọn eeyan nipamu Ijaabu awọn musulumi ti awọn akẹkọọ n wọ.
Ọsẹ meji gbako la gbọ pe igbimọ yii yoo lo lati fun ijọba ni esi agbeyẹwo wọn.
No comments:
Post a Comment