Idibo abẹle: Wahala ru yọ lẹgbẹ oṣelu APC l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 16, 2022

Idibo abẹle: Wahala ru yọ lẹgbẹ oṣelu APC l’Ogun


Beeyan ba wa nile ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, ẹka t’ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l’ọsan oni, ọjọ Ajẹ, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu karun-un, yoo mọ pe inu awọn ọmọ naa ko dun rara, pẹlu bi wọn ṣe fẹun kan awọn olori wọn, paapaa alaga ẹgbẹ naa n’ijọba ibilẹ yii, Ọnarebu Henry Fagbenro, wi pe o fẹẹ gbabọdi fun wọn.

Ko si ẹsun meji ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọọdu karun-un, wọọdu ẹjọ ati wọọdu kẹtala, bi ko ṣe pe wọn fẹẹ ṣe awuruju lori awọn orukọ ti wọn fi ranṣẹ s’awọn oloye ẹgbẹ gẹgẹ bi ọmọ igbimọ, iyẹn dẹligeeti ti yoo kopa ninu idibo abẹle lati yan awọn ọmọ oye fun idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.

Lakoko ti wọn n fẹhonuhan, wọn ni awọn ko le gba ki wọn gbe nnkan gba ẹyin wọn nipa yiyan le wọn lọwọ, nitori pe awọn mọ nnkan t'awọn n fẹ, ati pe awọn ti wọn f'orukọ wọn ranṣẹ l'awọn n fẹ.

Wọn ni pupọ ninu orukọ awọn ọmọ igbimọ ti wọn fi ranṣẹ ni awọn oloye ẹgbẹ naa ti yọ danu, ti wọn si fi awọn orukọ miran rọpo gbogbo rẹ, eyi lo si n bi awọn ọmọ ẹgbẹ ninu, ti wọn fi n rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria lati gba wọn.

Nigba to n f'esi, alaga ijọba ibilẹ ẹgbẹ naa, Ọnarebu Henry Fagbenro sọ pe gbogbo ọrọ ti wọn n sọ naa ko ri bi wọn ṣe sọ ọ, nitori pe oun ki i ṣe ẹni to le ṣe awuruju.

Ọnarebu Henry Fagbenro sọ pe o yẹ ki awọn to n fẹhonu han maa wadii ohun gbogbo daju, ko to di pe wọn gbe igbesẹ, to si ni igbesẹ ti wọn gbe yii ku diẹ kaato.

Nigba toun naa n sọrọ lorukọ alaga, Ọgbẹni Deji Kalẹjaye sọ pe iwe ẹsun ati ifẹhonuhan wọn l'awọn ti gbọ, to si fi da gbogbo wọn loju pe igbesẹ to tọ ni wọn yoo ṣe lori rẹ laipẹ.

O wa rọ gbogbo wọn wi pe esi ayọ ni wọn yoo gbọ, ti inu onikaluku yoo si dun.

Alaaji, Ọnarebu Ṣarafadeen Ogunwọlu toun naa lewaju awọn to lọ fẹhonu han sọ pe lotitọ loun ti ba alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun sọrọ, to si ni wọn ti n bẹrẹ igbesẹ lori ohun ti wọn n beere fun.







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI