Ẹgbẹ oṣelu APC fa Dapọ Abiọdun kalẹ lati kade du ipo lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 26, 2022

Ẹgbẹ oṣelu APC fa Dapọ Abiọdun kalẹ lati kade du ipo lẹẹkeji


Lonii, Ọjọbọ ti i ṣe Tọsidee ni gbogbo awọn oloye ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Ogun dibo yan Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ọmọ oye lati jade du ipo naa lẹẹkeji labẹ asia ẹgbẹ wọn.

Gomina Abiọdun la gbọ pe o lewaju awọn akẹgbẹ rẹ marun-un yooku, nibi to ti jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun-kan-le-ni-igba-din-diẹ, iyẹn 1168.

Awọn ti wọn du ipo lati gba tikẹẹti gomina ninu ẹgbẹ naa ni Gomina Dapọ Abiọdun, Ọnarebu Abdulkabir Adekunle Akinlade, Arabinrin Mọdele Sharafa-Yusuf, Onimọ-ẹrọ Biyi Ọtẹgbẹyẹ, Ọgbẹni Olurotimi Ọpalẹyẹ ati Ọgbẹni Rẹmilẹkun.

Nigba to n kede Dapọ Abiọdun, alaga igbimọ fun eto idibo abẹle ọhun, Ọnarebu Wale Ohu sọ pe ibo naa waye ni irọwọ-irọsẹ lai ṣe ojusaaju laaarin awọn to lẹtọọ lati dibo.

Bakan naa nigba toun naa n fi idunnu rẹ han lẹyin idibo ọhun, Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe inu oun dun gidigidi nitori pe awọn ọmọ ẹgbẹ APC n fẹ itẹsiwaju nipasẹ awọn iṣẹ ribiribi toun ti ṣe, ati eyi toun n ṣe lọwọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI