Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti sọ pe gbogbo aye familete-ki-n-tutọ ti ẹgbẹ oṣelu alatako nni, Peoples democratic Party, PDP n jẹ nipinlẹ Kwara ti d'opin, ko ti lee gberi mọ rara.
APC sọ pe gbogbo awọn iwa aib'ofin mu ati idari to n tapa si ofin ti iṣakoso PDP fi n jẹ gaba le awọn araalu lori lo ti d'ohun igbagbe patapata, nitori pe ẹgbẹ wọn ki i ṣe ẹgbẹ buruku, bi ko ṣe ẹgbẹ to n tẹle ilana ati ofin.
Nigba to n f'idi ọrọ naa mulẹ, Alaaji Tajudeen Fọlaranmi Aro to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara sọ pe kaakiri agbaye ni wọn ti f'ontẹ lu ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, gẹgẹ bi eyi to n tẹle ofin ati ilana, to si ti jẹ ko ye gbogbo ọmọ ipinlẹ naa wi pe ẹtọ araalu ko ṣee tẹ mọlẹ.
No comments:
Post a Comment