Ambasidọ rere ni Kunle Adeyanju jẹ - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 31, 2022

Ambasidọ rere ni Kunle Adeyanju jẹ - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun gbajugbaja ọkunrin to n wa alupupu igbalode (Power Bike) nni, Ọgbẹni Kunle Adeyanju lori bo ṣe gbe alupupu rẹ rin lati ilu Oyinbo wa si orileede Naijiria, eyi to fi n polongo didẹkun si ajakalẹ arun onigbameji, iyẹn Polio kaakiri ilẹ Afrika to pe ni
#EndPolio.
 
Ọjọ mọkanlelogoji la gbọ pe Adeyanju fi rin irin naa, lati polongo ọna lati dẹkun arun Polio ọhun.

Ninu atẹjade to gbe sita lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, AbdulRazaq ṣapejuwe Adeyanju gẹgẹ bi aṣoju rere, ẹni to ti fi ọgbọn ati oye rẹ, pẹlu itara si nnkan rere lati fi mu ayọ ati aabo ba ẹgbẹẹgbẹrun eeyan.

AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe oun tẹle gbogbo akitiyan Adekunle pẹlu bo ṣe rin irin ti ko din ni kilomita ẹgbẹrun mejila, kaakiri orileede ti ko din ni mẹrinla, to si pa ọrọ rẹ mọ nipa pipolongo didẹkun arun Polio.

Bakan naa lo wa fi kun ọrọ rẹ pe b'awọn ṣe ti n gbiyanju lati ri i pe awọn araalu wa ni ilera pipe, sibẹ awọn yoo tubọ maa polongo ọna lati dẹkun arun Polio naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI