Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ gbajugbaja oloṣelu, to tun jẹ ọkan lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nni, Oloye Olumide David Aderinokun ni kete ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo jade du ipo aṣofin agba l'ẹgbẹ naa.
Nibi eto idibo abẹle fawọn to fẹẹ jade du ipo aṣofin l'Abuja lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, eyi to waye ni gbọngan ayẹyẹ ti ile ikawe aarẹ, iyẹn Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii.
Wọn ni awọn oludibo mẹrindilogun-le-n'igba (216) lo kopa ninu eto idibo abẹle naa, nibi ti ida mọkandinlọgọrun ti dibo fun Aderinokun, ti awọn meji di dibo fun ẹni to ṣe ipo keji.
Nigba to n fi idunnu rẹ han, lẹyin ti ajọ eleto idibo, Independent Electoral Commission (INEC) to ṣakoso eto idibo abẹle ọhun kede rẹ gẹgẹ bi ọmọ oye, Aderinokun jẹ ko di mimọ pe ẹnu oun kun fun ọpẹ gidigidi.
O ni jijawe olubori oun ko ṣẹyin awọn ipa rere toun ti ko lawujọ, bẹrẹ lati ọdun 2019 titi di akoko yii, eyi to lo mu k'awọn eeyan dibo yan oun gẹgẹ bi ọmọ oye lẹgbẹ oṣelu PDP.
Bakan naa lo sọ pe, bo tilẹ jẹ pe oun ti bori ipele to kọgun si aṣekagba, sibẹ oun tun ṣi ni iṣẹ lati ṣe lati ri i pe ipo aṣofin ọhun ja m'oun lọwọ lọdun 2023.
No comments:
Post a Comment