AbdulRazaq ba Ọnarebu Ajuloopin kẹdun iku mama rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 16, 2022

AbdulRazaq ba Ọnarebu Ajuloopin kẹdun iku mama rẹ


Gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq ti ba Ọnarebu Tunji Ọlawuyi ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajuloopin kẹdun iku mama rẹ, Oloogbe, Alaaja Sifawu Ọlawuyi to jade late laipẹ yii.

Mama naa la gbọ pe o jade laye lẹyin aisan rampẹ to nii ṣe pe ọjọ ogbo.

Nigba to n fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si Ọnarebu Ọlawuyi, ẹni to jẹ aṣoju-ṣofin ipinlẹ naa niluu Abuja lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, Gomina AbdulRazaq sọ pe abiyamọ teeyan fi n tọrọ ni oloogbe naa jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI