2023: Ija oṣelu bẹ silẹ laaarin Dapọ Abiọdun ati OGD, l'Omiṣore ba sare lọ yanju ẹ fun wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 2, 2022

2023: Ija oṣelu bẹ silẹ laaarin Dapọ Abiọdun ati OGD, l'Omiṣore ba sare lọ yanju ẹ fun wọn


Orin 'ija d'opin, ogun si tan' ni gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel ati gomina to wa nibẹ lọwọlọwọ, Ọmọọba Dapọ Abiọdun n kọ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde ana, nibi ti akọwe agba fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore ti lọ ba wọn pari aawọ to wa laaarin wọn.

AWIKONKO gbọ pe o ti ṣe diẹ ti aawọ nla kan ti wa laaarin Gomina Dapọ Abiọdun ati Ọtunba Gbenga Daniel, iyẹn lori idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.

Wọn ni ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọtunba Ṣeyi Ọduntan ni Gomina Dapọ Abiọdun fẹẹ lo lati jade du ipo Sẹnetọ ti yoo ṣoju Ogun East l'Abuja.

Ipinnu Gomina Abiọdun yii ni wọn lo fẹẹ dabaru erongba Ọtunba Gbenga Daniel toun naa ti n mura silẹ lati du ipo ọhun.

Latigba ti wọn ni aṣiri yii ti tu si OGD lọwọ la gbọ pe ko ti gba ti Dapọ Abiọdun mọ, ti wọn si ni aarin awọn mejeeji daru patapata.

Eyi ni wọn lo mu ki OGD pinnu lati fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lati pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP to ti wa. Ṣugbọn lati ma ba a fa ariyanjiyan nla lo jẹ ko kọkọ ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC.

AWIKONKO tun gbọ pe idi ree ti wọn fi gbe Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore dide lati tete wa a ba Gomina Dapọ Abiọdun sọrọ nipa erongba rẹ lati gbe ẹlomiran dide fun ipo Sẹnetọ ti yoo ṣoju Ogun East l'Abuja.

Wọn ni bi OGD ba fi le kuro lẹgbẹ oṣelu APC, yoo ṣe ọpọlọpọ akoba fun ẹgbẹ naa lati padanu. Ati pe ipadasipo Gomina Abiọdun lẹẹkeji yoo tun lewu, nitori pe gbogbo awọn ọmọ ẹyin OGD ni wọn ko nii tẹle Dapọ Abiọdun mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI