Wọn láwọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ kọju sawọn oni Maruwa l'Agege l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 11, 2022

Wọn láwọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ kọju sawọn oni Maruwa l'Agege l'Ékòó


Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna laaarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde nigba ti wọn l'awọn oni mọto ti wọn wa labẹ Alaaji Musiliu Akinsanya, iyẹn MC Olúọmọ kọju ija sawọn oni Maruwa lagbegbe Agege nipinlẹ Eko, ti wọn si ṣe awọn eeyan leṣe.

A gbọ pe ṣe ni wọn yawọ agbegbe naa ti awọn oni Maruwa n duro si lati gbe ero, ti wọn si dabọn bolẹ nibẹ.

Wọn ni ojiji l'awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto naa yawọ ibudokọ awọn oni Maruwa yii, ti wọn dabọn bolẹ nibẹ, eyi to jẹ k'awọn eeyan ba ẹsẹ wọn sọrọ.

Ki oloju to o ṣẹ ẹ, wọn ni gbogbo agbegbe ọhun ti pa lọọlọ nigba ti awọn eeyan sa asala lati doola ẹmi ara wọn.

Ọpọ dukia la gbọ pe wọn bajẹ, ti wọn si tun dana sun Maruwa.

Bẹ o ba gbagbe, lati bi oṣu meloo kan sẹyin la gbọ pe awọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ ati ti Alaaji Azeez Abiọla ti ọpọ awọn eeyan mọ si Istijabah ti kọju ija sira wọn

Ọkan lara awọn oni Maruwa ti wọn dana sun Maruwa rẹ, Ọlagunju Rasheed nigba to n b'AWIKONKO sọrọ ṣalaye pe inu ṣalanga loun wa, iyẹn nibi toun ti n yagbẹ lọwọ, ko to di pe wahala naa bẹ silẹ.

Ọlagunju sọ pe ka loun ko si ni ṣalanga naa, oun naa ko ba ti juba ehoro, ki wọn si ma raaye dana sun Maruwa oun.

Siwaju sii lọkunrin naa bu ẹnu atẹ lu iwa ti awọn oni mọto naa hu, to si ni awọn kii ṣe ọmọ ẹyin MC Olúọmọ bi ko ṣe ti Istijaba toun n ṣakoso Maruwa l'Ekoo.

Ọlagunju Rasheed

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Bi mo ṣe n bọ laaarọ yii, inu n ko mi, mo ni lati ya si ṣalanga. Mi o paaki sibi ti a ti n gbero, abẹ igi ni mo lọ gbe Maruwa mi si, ti mo fi lọ yagbe.

"Ibẹ ni mo wa ti mo ti n gbọ ariwo pe wọn ti n yinbọn. Ọmọ to ri mi nigba ti mo wọ ṣalanga lo wa pe mi, to si n pariwo Eko, nitori pe orukọ ti ọpọ awọn eeyan mọ mi si niyẹn.


" O ni wọn ti fẹẹ dana sun Maruwa mi, bi mo ṣe sare jade niyẹn. Mo ri wọn bi wọn ṣe n dana sun Maruwa mi, ṣugbọn mi o le sunmọ wọn, ki wọn ma ba a pa mi. Mi o mọ wọn ri tẹlẹ, ṣugbọn mo le da wọn mọ bi mo ba ri wọn.

"Awọn ọga wa ni wọn jọ n ba ara wọn fa wahala, mi o wa mọ idi to fi kan awa. Mi o si lara awọn oloye ẹgbẹ. Kani mi o si ni ṣalanga, emi naa ko ba ti salọ. Mo fẹ ki ijọba ipinlẹ Eko ran mi lọwọ, nitori pe Maruwa yii ni mo fi n bọ iyawo ati ọmọ, ko si ọna miran."

Gbogbo akitiyan lati ba Bẹnjamin Hundeyin to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ja si pabo ti di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI