Tanka elepo meji to gbina tun f'ẹmi ṣ'ofo l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 7, 2022

Tanka elepo meji to gbina tun f'ẹmi ṣ'ofo l'Ogun


Tanka elepo rọbii kan ni iroyin tun ti fi to wa leti wi pe o ti ṣakoba fun ọpọ awọn eeyan, eyi to mu ẹmi eeyan kan lọ, ti ọpọ dukia si ṣofo danu loju ọna Ijẹbu-Ode si Ibadan, ipinlẹ Ogun.
 
Alẹ ana, Wẹside, Ọjọru la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye, gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ṣabojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa, TRACE ṣe fi to wa leti.
 
AWIKONKO gbọ pe iwaju ilẹ adura ti awọn Musulumi, eyi ti wọn pe ni NASFAT n'iṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to wa leti.
 
Wọn ni ṣe ni awakọ tanka epo rọbii naa sọ ijanu rẹ nu lori ere, to si ṣe bẹẹ ṣubu lulẹ, ko to di pe o gbina lojiji. Wọn ni ibi ti awakọ tanka elepo miran toun naa n kọja lọ ti ri iṣẹlẹ yii, lo ti pinnu lati ṣe iranwọ.
 
Iyalẹnu lo jẹ pe nibi ti wọn ti n du u lati pa ina yii ni tanka keji naa tun gbina, eyi to jẹ ki awọn to wa nibẹ sun sẹyin.
 
Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi nigba to n f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe ọganjọ oru niṣẹlẹ naa waye, ti eeyan kan to jẹ ọkunrin si ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
 
Akinbiyi ni bo tilẹ jẹ awọn ko le fidi ẹni to padanu ẹmi rẹ sinu ijamba yii mulẹ, ṣugbọn to ni ki awọn oṣiṣẹ wọn to debẹ, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI