Ọwọ ọlọpaa tẹ ọrẹ mẹta to n jale ninu gosiloo l'Ekoo pẹlu ibọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 7, 2022

Ọwọ ọlọpaa tẹ ọrẹ mẹta to n jale ninu gosiloo l'Ekoo pẹlu ibọn


Ibudokọ Toyota to wa l'agbegbe Oṣhodi, n'ipinlẹ Eko lọwọ palaba awọn ọrẹ mẹta ti wọn n'iṣẹ meji ju adigunjale kaakiri igboro ilu Eko lọ ti segi. Awọn ọlọpaa pajawiri ti a mọ si Rapid Response Squad (RRS) lo rọwọ to wọ lọjọ karun-un, oṣu ti a wa yii.
 
Ibọn ilewọ kan pẹlu ọta ibọn mẹrin ọtọọtọ ni wọn gba lọwọ wọn ni kete ti ọwọ tẹ wọn, to si jẹ pe ṣe ni wọn n rababa bẹbẹ fun idariji.
 
 
 
Omuyibo Goddey, ọmọ ọdun mejilelọgbọn ti wọn n pe ni Aro Ghetto Boy; Destiny Nwanga, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ti wọn n pe ni Aro Smiling God; ati Ebuka Igwe, ọmọ ọdun mẹtalelogun ti wọn n pe ni Aro Do or Die l'awọn mẹtẹẹta ti wọn ha.

Wọn lawọn mẹtẹẹta yii, ogbologbo ni wọn jẹ ninu ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Aro–Baga.
 
Goddey, nigba tọwọ tẹ ẹ, lo jẹwọ pe ẹnikeji lawọn fẹẹ ja lole ko to di pe ọwọ tẹ awọn. Oun lo si mu awọn ọlọpaa lọ si ibi ti ọwọ ti tẹ awọn yooku lojule keje, adugbo Alaaji Mọnsuru, Ijegun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI