Lati le mu ki ounjẹ ọfẹ lọ deedee lawọn ile-ẹkọ alakọbẹrẹ kaakiri orileede Naijiria, gẹgẹ bi ilana, ijọba apapọ ti gbe eto idanilẹkọọ kalẹ fun gbogbo awọn alase ti ko din ni mejilelọgbọn nipinlẹ Kwara lori ọna ti wọn yoo maa gba dana ounjẹ f'awọn akẹkọọ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni gbogbo awọn alase ti wọn yege lati maa dana ounjẹ f'awọn akẹkọọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ kaakiri ipinlẹ Kwara ṣe idanilẹkọọ naa, ṣaaju ọjọ ti eto ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu.
Ileeṣẹ ijọba papaọ kan ti wọn pe ni National Documentation and Training of Cooks on the National Home-Grown Feeding Programme to wa labẹ akoso ileeṣẹ ijọba ti Federal Ministry of Humanitarian Affairs and Disaster Management and Social Development la gbọ pe o gbe idanilẹkọọ naa kalẹ.
A gbọ pe awọn alase meji-meji ni wọn mu n'ijọba ibilẹ kọọkan to wa n'ipinlẹ Kwara, ti wọn si gba wọn lamọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ lai ṣe ojusaaju.
No comments:
Post a Comment