Oriire Onibeji: Lẹyin to gba awọọdu Nelson Mandela, Yinka Fafoluyi, amugbalẹgbẹẹ Gomina AbdulRazaq tun di ambasadọ ECOWAS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 9, 2022

Oriire Onibeji: Lẹyin to gba awọọdu Nelson Mandela, Yinka Fafoluyi, amugbalẹgbẹẹ Gomina AbdulRazaq tun di ambasadọ ECOWAS


Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ amugbalẹgbẹẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lori ọrọ iroyin igbalode, Ọgbẹni Fafoluyi Ọlayinka Michael lori bo ṣe gba ẹbun nla meji ọtọọtọ ti ko wọpọ.

Fafoluyi, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Solace la gbọ pe wọn fi aami ẹyẹ meji ọtọọtọ yii da lọla lati fi mọ riri ipa to n ko lawujọ awọn ọdọ, paapaa lẹka eto iroyin igbalode.


Ninu lẹta kan ti aarẹ ẹgbẹ ECOWAS, ẹka ti awọn ọdọ, Ambasadọ Emmanuel S. William bu ọwọ lu lati fidi rẹ mulẹ wi pe lotitọ l'awọn fi ipo naa da Solace lọla lo ti jẹ ko di mimọ pe aṣaaju rere to ṣee fi ọkan tan ni.

Solace nigba to n fi idunnu rẹ han, o sọ pe oun fi awọn aami ẹyẹ meji pataki naa jin fun Ọlọrun ati fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq to tọ oun dagba, ẹni to tun foun lanfaani lati di ipo naa mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI