Kwara: Ẹ maa gbaradi fun idibo abẹle to ṣoju-ṣaara, alailabawọn - APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 16, 2022

Kwara: Ẹ maa gbaradi fun idibo abẹle to ṣoju-ṣaara, alailabawọn - APC


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti gba gbogbo awọn to n gbero lati gbe apoti ibo l'ọdun 2023 lati gbaradi fun idibo abẹle to n bọ lọna yii, ti wọn ti ni gbogbo eto lo ti pari lẹkunrẹrẹ.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Alaaji Tajudeen Afọlaranmi Aro fi sita laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ko nii si ojusaaju ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to n bọ lọna yii, ati pe onikaluku ni wọn yoo fun lanfaani lati kopa.

Aro sọ pe niwọn igba ti ọpọ ọmọ ẹgbẹ naa ko ti gba lati fẹnu ko lori oludije kan tabi ekeji wi pe ki wón fa kalẹ, eyi ti wọn n pe ni Consensus, o ni idibo abẹle naa yoo waye nirọwọ irọsẹ.
 
Bẹẹ lo sọ pe ki gbogbo awọn to ba fẹẹ jade du ipo oṣelu tete lọ gba fọọmu lati dije nileeṣẹ ẹgbẹ naa ni kete ti wọn ba ti bẹrẹ gbigbe fọọmu jade, ati pe ko si erongba lati pa ẹnikẹni lẹnu mọ ninu eto idibo naa.
 
O tẹsiwaju pe idibo to ṣoju ṣaara, alailabawọn ni ẹgbẹ naa ti pese silẹ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ pẹlu eto aabo to peye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI