Awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara ti rawọ ẹbẹ si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq wi pe ko dide lati gbe igbesẹ ti yoo fi ra mọto fun gbogbo awọn kọmiṣanna rẹ patapata, nitori pe wọn yẹ lati gba mọto irinsẹ ijọba.
Wọn pe ipe naa laipẹ yii lati fi mọ riri iṣẹ ti awọn kọmiṣanna naa n ṣe ni oniruuru ẹka ipo ti wọn yan wọn si, ti wọn si ni ohun irinsẹ ṣe pataki pupọ fun wọn.
Bakan naa ni wọn gbe oriyin ati oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori awọn iṣẹ takuntakun to n mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ Kwara latigba to ti gbajọba.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ọkan lara awọn to maa n sọ bo ṣe n lọ lagbo oṣelu ati ohun to n lọ kaakiri orileede, eyi ti awọn eeyan n pe ni Public Analyst fẹsun kan ijọba lori redio Sobi ko sọrọ sita ko to ra awọn mọto Geely Coolray SUV.
Lara awọn to sọrọ naa sọ pe:
Ko si nnkan to buru ninu rira mọto f'awọn kọmiṣanna, ti wọn ti fi tọkantọkan sin ipinlẹ wọn fun ọdun mẹta gbako. Idagbasoke to yẹ ni, ti ko si yẹ ki wọn maa fi ṣe ti oṣelu, nitori pe ko bu iyi to tọ fun Kwara lati gbọ pe awọn Kọmiṣanna wọn ko ni mọto fun ọdun mẹta. Gomina n ṣiṣẹ takuntakun to si n na awọn owo to han si gbogbo ilu latigba to ti bẹrẹ awọn akanṣe iṣẹ, ko si yẹ ko wa jẹ pe rira mọto f'awọn kọmiṣanna ni yoo jẹ ohun babara, ko si yẹ ko digba ti wọn ba n kede sita gbangba ko to di pe wọn fun wọn. - Oṣiṣẹ ijọba.
Idagbasoke yii ko yẹ ko jẹ ohun ti a maa gba bi ẹni to gba igba ọti, nitori pe ohun to yẹ ni. Nigba ti Ọmọwe Bukọla Saraki ati Alaaji Abdulfatah Ahmed wa nijọba, wọn raawọn mọto bọginni f'awọn kọmiṣanna ati awọn amugbalẹgbẹẹ to fi mọ oludamọran pataki lai si wi pe ẹnikẹni n bu ẹnu atẹ lu wọn. - Alaaji Saka AbdulWaheed, Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Rira mọto fun awọn Kọmiṣanna ti di ojuṣe ijọba, nitori pe ohun to tọ ni, ko wa yẹ ki ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq yatọ rara. - Julius Adeyemo
No comments:
Post a Comment