Ṣe lọrọ naa dabi ẹfun ati eedi nigba ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ Kwara, Peoples Democratic Party, PDP koju ija sira wọn, ti wọn si bẹrẹ sii ba dukia ati ile ẹgbẹ wọn jẹ.
Awọn kan tiẹ sọ pe asasi lo mu wọn pẹlu bi wọn ṣe n fojoojumọ ba ara wọn ja, ti wọn ko si gba itọ ara wọn dami, eyi to mu ki wọn wọgile ipade awọn wọọdu to yẹ ko maa waye kaakiri ipinlẹ naa.
Ko si nnkan meji ti wọn lo n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ naa, paapaa nipinlẹ Kwara bi ko ṣe ti ọrọ awọn ọmọ oye ti wọn fẹẹ fa kalẹ lati jade du ipo oṣelu.
Wọn ni latigba ti Gomina ipinlẹ naa tẹlẹri, Bukọla Saraki ṣe fun gbogbo awọn alatilẹyin rẹ to n fẹ ni fọọmu erongba lati jade du ipo, ni wahala ti bẹrẹ sii ṣẹlẹ lọkan-o-jọkan nipinlẹ ọhun.
No comments:
Post a Comment