Ẹ ṣora o! Ọdalẹ nla ni Tolu Ọdẹbiyi ati GNI – Yayi pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 30, 2022

Ẹ ṣora o! Ọdalẹ nla ni Tolu Ọdẹbiyi ati GNI – Yayi pariwo sita


Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun ipinlẹ Eko nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, Sẹnetọ Sọlomọn Ọlamilekan Adeọla ti fẹsun kan Ṣenetọ to n ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun ipinlẹ Ogun, Tolu Ọdẹbiyi ati oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun lẹẹmẹta ọtọọtọ, Gboyega Nasiru Isiaka gẹgẹ bi ọdalẹ ti ko ṣe e f’ọkan tan, paapaa nidii ọrọ eto oṣelu.
 
 
Gbajugbaja Sẹnetọ naa ti ọpọ awọn eeyan mọ si Yayi lo sọrọ naa laipẹ yii lakoko to n b’AWIKONKO sọrọ nile ẹ to wa niluu Ilaro, ipinlẹ naa, to si ni Ọlọrun lo n gbe ohun bori awọn ọta oun nidii ọrọ oṣelu ipinlẹ ọhun.
 
Lakoko to n sọrọ rẹ, Yayi sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko kabamọ pe oun ṣe iranwọ f’awọn mejeeji yii, sibẹ iyalẹnu lo n jẹ wi pe wọn le gbe iru igbesẹ ti wọn gbe naa.
 
Nigba to n sọrọ nipa Sẹnetọ Ọdẹbiyi, o loun ko mọ pe ọkunrin naa le tun pada lọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọta to ṣiṣẹ tako o lakoko eto idibo to kọja lọ, ko si wa f’oju gbogbo awọn to ran an lọwọ lati de ipo Sẹnetọ gbolẹ, eyi to ni iwa ti ko ba ojumu to ni.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe:
 
Nigba ti Tolu Ọdẹbiyi de, Amosun paṣẹ pe ki gbogbo wọn lọ sinu ẹgbẹ APM, ṣe lo sọ pe oun ko lọ, ati pe ibi ti Gomina Amosun ba duro loun naa yoo duro. Gomina Amosun sọ pe kii ṣe ọmọ ẹyin rere, o si paṣẹ pe ki gbogbo awọn yooku lọ si APM lati ṣiṣẹ tako Tolu Ọdẹbiyi.
 
Funra Tolu lo wa ba mi lati ṣalaye iṣoro rẹ fun mi. Mo gbaruku tii nipa owo ati atilẹyin gidi, mo si sọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹyin mi lati dibo fun un, ki wọn ran an lọwọ de ipo Sẹnetọ. Ṣugbọn ṣa, o ṣeni laanu wi pe nigba to de ipo naa, ipele awọn eeyan akọkọ to maa ba ja l’awọn to ran an lọwọ lati de ipo naa. O sọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APM lati parapọ, ati pe oun ko fẹẹ gbọ orukọ kankan to ba n jẹ Yayi nijọba ibilẹ naa mọ.
 
Mo pe e, mo si beere lọwọ ẹ. Lẹyin-o-rẹyin, o ja awọn eeyan naa kulẹ, o si pada s’ọdọ Amosun ati mọlẹbi APM rẹ. Emi naa si pada wa lati gba awọn eeyan mi pada. Kin ni mo wa ṣe ti ko dara? Ti mo ba fi awọn eeyan naa silẹ ninu otutu, ti wọn wa lọ darapọ mọ ẹgbẹ miran, adanu nla ni yoo jẹ fun mi.
 
Awọn ti wọn ṣiṣẹ tako ẹ, to wa jẹ pe awọn n lo n ṣe fun bayii, wọn wa n gbadun lẹyin ti wọn dibo fun ẹlomiran lati tako ẹ, nitori ti o gbagbọ pe mo n pada bọ ninu ilana naa, ti Gomina Dapọ si n gbe mi gẹgẹ. Ki eeyan to le gbe iru igbesẹ yii, iru ẹni bee ni lati gbe iwọn oṣelu ara rẹ yẹwo daadaa, ko ma ba a kuna. Mi o ro pe ohun ti mo ṣe ko dara. Mi o tii ṣẹ si ẹnikẹni.
 
Tolu tun ṣe nnkan to buru jai fun mi, ṣugbọn mo pinnu lati ma sọrọ ni. Bawo ni Tolu Ọdẹbiyi yoo ṣe le pe mi ni ọmọ ale niwaju awọn akẹgbẹ wa l’Abuja? Mo wa beere pe, ṣe nitori pe orukọ baba mi kii ṣe ‘Ọlabimtan’ lo ṣe n pe mi ni ọmọ ale?
 
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ninu itan awọn to n ṣoju ẹkun Yewa nile igbimọ aṣofin agba l’Abuja, ko ti i si ẹni to lọ sipo naa lẹẹmeji, o ni bi Tolu ba n gbiyanju lati pada lọ lẹẹkeji, ṣe lo kan n tan ara rẹ jẹ lasan ni, nitori pe itan ko le yipada lori rẹ. O ni ki Tolu lo maa palẹmọ ẹru rẹ lati pada sile to ti wa.
 
Sẹnetọ Yayi nigba to n sọrọ nipa ohun ti oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun llati ẹkun Yewa, iyẹn Gboyega Nasiru Isiaka ṣe, lakoko toun n gbero lati wa du ipo nipinlẹ naa, ṣe loun n pe ipade pẹlu ẹ si Eko, ki wọn le jọ sọ asọyepọ, ṣugbọn to jẹ pe nigba ti ọrọ ko ri bi wọn ṣe ro o mọ, ṣe ni GNI lọ n ba oun lorukọ jẹ kaakiri.
 
O sọ ninu ọrọ rẹ siwaju pe:
Ni ti Gboyega Nasiru Isiaka bakan naa, nigba ti mo n gbe igbesẹ lati jade du ipo gomina ipinlẹ yii, ẹẹmeji ọtọọtọ ti wọn pe mi lati pada s’Ekoo jẹ ọwọ nla ti mo bu f’awọn aṣiwaju wa ni. Gbogbo awọn ti wọn ti ran mi lọwọ lati jẹ ki n jẹ eeyan laye ni wọn sọ pe ki n pada s’Ekoo nigba ti wa lati gbe apoti ibo l’Ogun. 
 
Ẹ lọ beere lọwọ GNI daadaa, mo gbe ipade kalẹ laaarin emi pẹlu ẹ l’Ekoo. Agbegbe Alausa ni Ikẹja lati ṣe ipade ọhun. Ki la n ṣe lawọn ipade yii? Ṣe la n gbiyanju lati mọ ara wa deledele, ka si jọ sọ asọyepọ, nigba ti ipinnu igbẹyin waye, awọn adari sọ pe ki n pada s’Ekoo, mo si sọ fun GNI.
 
Lara awọn to kọkọ ba sọrọ, ohun ti GNI sọ fun wọn ni pe ‘a ti fi oro le Yayi pada s’Ekoo’. Ṣe ni wọn fi n ṣe yẹyẹ wi pe ki lo de ti ko pe Yayi, lati pe e sinu ẹgbẹ rẹ, ko si gbaruku tiẹ. To ba maa ṣe bẹẹ, boya lonii ni. Gbogbo wa la mọ ipo ti GNI di mu nipinlẹ Ogun lonii. Ibo ni mo ti wa ṣe ohun to buro. Ti bi mo ṣe n wa yii ba n ba wọn lẹru, nnkan miran niyẹn lọtọ.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI