Ẹ gba lọwọ MC Oluọmọ o! Tikẹẹti meji ọtọọtọ la n ja lojumọ bayii – Awọn oni Maruwa pariwo sita l’Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 26, 2022

Ẹ gba lọwọ MC Oluọmọ o! Tikẹẹti meji ọtọọtọ la n ja lojumọ bayii – Awọn oni Maruwa pariwo sita l’Ekoo


Gbogbo awọn awakọ Maruwa kaakiri agbegbe Ile-Epo, Abule-Ẹgba, to fi mọ Ẹkọrọ ni wọn ti jade sita lọpọ yanturu lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nibi ti wọn ti n fi ẹhonu han lori bo ṣe jẹ pe tikẹẹti meji ọtọọtọ ni wọn n ja bayii.

Nibi iwọde ifẹhonu han naa la gbọ pe awọn awakọ Maruwa l’awọn agbegbe wọnyi ti fẹsun kan Alaaji Musiliu Akinsanya, iyẹn MC Oluọmọ, ẹni to jẹ alaga awọn awakọ l’Ekoo wi pe oun lo wa nidi bi wọn ṣe n ja tikẹẹti meji lojumọ bayii.


Wọn ni MC Oluọmọ lo wa nidi b’awọn oni Maruwa ṣe n ja tikẹẹti meji lakoko yii, nitori pe gbogbo awọn ọmọ ẹyin ẹ ni wọn lo n fi agidi kan an nipa f’awọn lati maa ja tikẹẹti ti ki i ṣe tiwọn.

Ọkan lara awọn onimaruwa to fẹhonu han nigba to n b’AWIKONKO sọrọ ṣalaye pe bi ẹni pe wọn mọ-ọn mọ n fiya jẹ awọn ni, nitori pe tikẹẹti t’awọn n ja lojumọ ti pọ ju.


Ẹni naa sọ pe iru nnkan bayii ko ṣẹlẹri ko to di pe awọn ọmọ ẹyin MC Oluọmọ wa bẹrẹ si i fipa mu wọn. Bẹẹ lo sọ pe awọn ko mọ Oluọmọ si ọga awọn, bi ko ṣe pe mọto loun n bojuto.

“Ẹ jọwọ, ẹ gba wa lọwọ MC Oluọmọ. Owo ti wọn n gba lọwọ wa lagbegbe Ile-Epo, Abule-Ẹgba, Ẹkọrọ ti pọ ju agbara wa lọ. Bi a ba de garaaji Maruwa ni Ile-Epo, a maa ja tikẹẹti, bi a ba tun ṣiṣẹ de Ẹkọrọ ati Abule-Ẹgba, a tun maa ja tikẹẹti nibi mejeeji yii. O wa jẹ tikẹẹti mẹta lojumọ, eyi ti pọ ju.” Ọkan lara awọn onimaruwa pariwo sita.


“A fẹẹ bẹ gbogbo ọmọ Naijiria lati ba wa ba ijọba ipinlẹ Eko sọrọ, nitori pe nnkan to n ṣẹlẹ lagbegbe Alimọṣhọ, Agbado, Oke-Odo wi pe gbogbo awa ti a n wa Kẹkẹ ko raaye ṣiṣẹ mọ.

“Awọn ọmọ ẹyin MC Oluọmọ ni wọn n da wa laamu. Wọn ti fọ gilaasi ọkan lara awọn ti a jọ n ṣiṣẹ. Ki ijọba Eko ṣaanu wa, ki wọn tete ba wa da si ọrọ yii. Lati bi ọsẹ kan sẹyin la ti n sa kaakiri nitori wahala yii.


“Wọn lu mu, wọn tun lu ọkan lara awọn ti a jọ n ṣiṣẹ fọ loju. Ẹ ṣaanu wa nitori pe nnkan ti a maa jẹ la n wa o.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI