Ijọba ipinlẹ Kwara laipẹ yii ti fidi rẹ mulẹ wi pe ko si otitọ kankan ninu ahesọ to n lọ kaakiri nipa wi pe awọn ya owo kan to to miliọnu mẹtalelaadorun-un naira nibi kankan.
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna f'ọrọ eto ibaraẹnisọrọ, Ọnarebu Bọde Towoju fi sita lo ti sọ pe irọ to jinna si otitọ ni Ọnarebu Saheed Popoọla sọ.
Laipẹ yii ni Ọnarebu Saheed Popoọla sọ nibi ifọrọwerọ kan to ṣe lori redio pe biliọnu mẹtalelaadorun-un ni ijọba Kwara ti ya latigba ti wọn ti de ijọba lọdun 2019.
Ọnarebu Towoju sọ pe ko si otitọ kankan ninu awọn ọrọ naa, nitori pe gbogbo owo ti ijọba n na lori ipinlẹ naa ni ko si eyi to bo, ati pe gbogbo rẹ lo wa nita fun aridaju.
No comments:
Post a Comment