Ogbontarigi Amofin lorileede Naijiria, Amofin Fẹmi Falana ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo eeyan lo lẹtọọ lati ṣe ẹsin to ba wuu labẹ ofin, paapaa awọn Onifa to fi mọ Babalawo.
Ọjọ Abamẹta, Satide tii ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹrin, ọdun 2022 ni Amofin Falana sọrọ yii niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, nibi ifilọlẹ ẹgbẹ Ijọ awọn Onifa niluu Ẹgba, nibi ti gbogbo awọn Babalawo kaakiri ilu Abẹokuta ti peju-pesẹ.
Amofin Falana sọ pe ninu abala kejidinlogoji iwe ofin Naijiria, o wa nibẹ wi pe onikaluku lo lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe oniruuru ẹsin to ba wuu lai si idiwọ kankan nibẹ.
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu bi ile ẹjọ kan nipinlẹ Kano ṣe ju ọmọ ọkunrin kan, Mubarak Bala sẹwọn ọdun mẹrinlelogun nitori ainigbagbọ Ọlọrun, to si ni ko yẹ ki iru nnkan bẹẹ maa ṣẹlẹ.
O wa gba gbogbo awọn Babalawo lamọran lati dide ji giri, ki wọn si wa gbogbo ọn ati wọn yoo fi tun orukọ wọn t’awọn eeyan buruku ti bajẹ nipa oogun owo ṣiṣe, to si ni titẹ ipa mọ iṣẹ nikan ni oogun owo to daju, kii ṣe nipa pipaayan lati fi ṣoogun owo.
Nibi eto yii ni wọn ti fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni iwe ẹri ati kaadi idanimọ gẹgẹ bi ojulowo ọmọ ẹgbẹ, ti wọn si tun yan igbimọ ẹlẹni meje, iyẹn Task Force ti yoo ṣawari awọn to jẹ ayederu Babalawo, ati igbimọ ẹlẹni mejilelogun, Disciplinary Committee, lati fi iya to tọ jẹ awọn oniwa ibajẹ labẹ ofin.
Ninu ọrọ Amofin Fẹmi Falana, o sọ pe “Ẹgbẹ yin lẹtọọ labẹ ofin, ẹyin ọmọ ẹgbẹ, gbogbo yin lẹ lẹtọọ labẹ ofin lati pejọ ṣe Ifa n’ipinlẹ Ogun ati ni gbogbo Naijiria. Bi awọn Kritẹẹni ṣe wa, lawọn Musulumi naa wa, awọn Babalawo naa wa. Gbogbo yin lẹ lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe nnkan ti ẹ fẹẹ ṣe, lati ṣe ipade, lati d’Ifa f’awọn to ba n wa.
Amofin Falana tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ọpọ awọn oloṣelu ati aṣoju ijọba ni wọn n ya ile Babalawo lati wa agbara, ati pe ẹsin igbagbọ ati musulumi ko sọ pe ki a ma beere aabo lọwọ awọn oniṣẹṣe, iyẹn bi ko ba ti ni la ẹmi eeyan lọ.
O ni awọn amookunṣeka, ọbayejẹ ati kọnda ninu irẹsi ni wọn sọ awọn Babalawo ni orukọ buruku, eyi to ni ki awọn naa dide bayii lati ja fun ẹtọ wọn, ki wọn si foju gbogbo awọn to n f'iṣẹ naa lu jibiti han sita.
“Bi ẹ ba mu awọn danadana, ajinigbe tabi ajinigbe, ti ẹ mu wọn de ile ẹjọ tabi lọdọ awọn ọlọpaa, ti ẹ wa ri onde tabi ifunpa lara wọn, wọn a sọ pe Babalawo lo ṣe e fun wọn ki ọwọ ọlọpaa ma ba a tẹ wọn. Awọn gbọmọgbọmọ tun n lo o lati fi ṣoogun owo, bi ẹ ba beere lọwọ awọn naa, wọn a sọ pe awọn ni Babalawo.
“Fun idi eyi, ẹ ni iṣẹ pupọ lati ṣe. Iṣẹ ti ẹ si maa ṣe fun ara yin ati fun ilu ni pe ẹgbẹ yin kii ṣe ẹgbẹ apaayan, kii ṣe ẹgbẹ awọn to n ṣe oogun owo. Ẹni to ba n tan ara rẹ jẹ lonii, to sọ pe o digba ti oun ba gba ẹjẹ eeyan ko to lowo, ẹni to yẹ ki wọn fi si ahamọ ni o, ko si foju ba ile-ẹjọ."
O rọ wọn lati dẹkun nipa ṣiṣe oogun fun awọn ọdaran bii danadana, adigunjale, ajinigbe.
Ko si nnkan to n jẹ oogun owo
Falana fi kun ọrọ rẹ pe ko si nnkan to n jẹ oogun owo, ati pe to ba jẹ pe lotitọ ni oogun owo wa, ọpọ awọn eeyan ni ko nii ṣiṣẹ mọ, to si ni wọn kan n da ẹmi awọn eeyan legbodo lasan ni nipa ẹtanjẹ owo ojiji.
Ẹsin kan ko ga ju ọkan lọ
Amofin agba naa tun tẹsiwaju pe ko si ẹsin to ga ju ekeji lọ labẹ ofin, ati pe ẹtọ kan naa ni onikaluku ni, to si ni ki gbogbo wọn jade lati f'ọwọ sọya nipa ẹsin wọn, ati pe bi wọn ba ti n tẹle ofin, ko si ibẹru kankan fun wọn.
"Bi ẹ ba ti n tẹle ofin nilẹ yii, ko si ibẹru kankan fun un yin. Labẹ ofin, ọmọ orileede Naijiria lẹtọọ lati sin Ọlọrun tabi Olodumare tabi Ifa. O tun wa ninu iwe ofin Naijiria wi pe ijọba ko gbọdọ fọwọ si ẹsin kankan. Gbogbo wa la lẹtọọ lati sin Ọlọrun, yala Jesu, Anọbi tabi Ifa to ba wu wa labẹ ofin.
“Nitori naa, bi ijọba ba ṣe nnkan fun Kritẹẹni tabi Musulumi, wọn gbọdọ ṣee fun ẹyin naa, kii ṣe Naijiria nikan ni wọn ti n ṣe Babalawo. Nigba ti mo kọkọ lọ si Cuba, Ifa ni wọn n da nibẹ. Gbogbo awọn oriṣa to ti ku ni Naijiri ko ku ni Cuba ati Brazil. Nibẹ ni mo ti mọ pe Ifa maa n sọrọ, ti awọn eeyan si n gbagbọ. Gbogbo awọn Oriṣa yii ni wọn ṣe ere fun. Bi wọn ba n ṣe Oro ni Brazil, gbogbo ilu lo maa jade.
“Iṣẹ pọ lọwọ, iṣẹ ti mo si n fun un yin lonii ni pe ki ẹ lọ bẹrẹ bi ẹ ṣe maa tun orukọ yin ṣe, awọn eeyan buburu ti ba orukọ ẹgbẹ yin jẹ. Iṣẹ keji si ni pe, ẹ ni lati mọ pe kii ṣe Naijiria nikan ni wọn ti n ṣe ẹgbẹ yin, fun idi eyi, ẹ ni lati mọ ohun to n ṣẹlẹ lẹyin odi, iyẹn gbogbo awọn ibi ti wọn ti n da Ifa.”
Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi naa sọrọ nipa oogun owo
Ki eeyan to le jẹ Babalawo, mo ro pe o gbọdọ kọ iṣẹ yẹn nibi kan, eeyan ko le ji lọjọ kan, ko sọ pe Babalawo loun, nitori pe eeyan ko le deede ji lọjọ kan lati sọ pe ọlọpaa loun, lai gba ile-ẹkọ ọlọpaa kankan kọja, aṣiri rẹ yoo tu nibi imura rẹ, ti a si maa n fi ọwọ ofin mu iru wọn. Iya to ba si yẹ ko jẹ iru ẹni bẹẹ ni ile-ẹjọ mmaa fi jẹ ẹ.
Bi awa ba le maa mu awọn to jẹ ayederu ọlọpaa, ko si ohun to da awọn Babalawo duro lati maa fi ọwọ ofin mu awọn to jẹ ayederu laaarin wọn. Ẹ pe ẹni to ba pe ara rẹ ni Babalawo lati beere ibi to ti kọ iṣẹ tiẹ, ati Babalawo to kọ ọ niṣẹ.
Awọn ayederu yii ni wọn n ba iṣẹ ti ẹ n ṣe jẹ fun un yin. Wọn mọ pe awọn ko lorukọ, ṣugbọn wọn n wa ọn alati ba orukọ olorukọ jẹ lasan ni. Laipẹ yii la ri awọn ọmọ keekeeke ti wọn lawọn fẹẹ ṣoogun owo, wọn lawọn rii lori ẹrọ ayelujara ti fesibuuku ni, a ṣe iwadii, a si ba bẹẹ lotitọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe kinni naa kuro lori fesibuuku, sibẹ bi aja wọn ba pe ogun ọdun laye, ẹran ogun ni gbogbo wọn nitori pe ọwọ yoo tẹ wọn. Iru awọn wọnyi ni wọn n ba iṣẹ Babalawo jẹ. Eeyan kan le fi gbogbo ẹnu sọ pe oun n bọ lati ọdọ Aafa oun ni, ki ẹlomiran sọ pe oun n bọ lati ọdọ Pasitọ oun ni, ẹ ko le ri eeyan ko sọ pe oun n bọ lati ọdọ Babalawo oun ni. Idi ni pe wọn ti n fi oju eeyan buruku wo gbogbo awọn to jẹ Babalawo ni, ko si yẹ ko ri bẹẹ.
Idi ti a fi da ẹgbẹ ijọ Onifa Babalawo silẹ
Oludasilẹ ẹgbẹ naa, Oloye Ifadimeji Jegbe Biobaku nigba to n sọ idi ti wọn fi da ẹgbẹ naa silẹ labẹ ofin sọ pe ọlaju to de nipa awọn ẹsin mejeeji ti jẹ ki wọn maa fi oju buruku wo ẹsin abalaye, to si ni ko yẹ ko ri bẹẹ.
Biobaku ni awọn ko le tori ọlaju to de, ki wọn wa tẹri ẹsin ajogunba ba, ati pe nitori wi pe awọn ko ti i fi orukọ silẹ labẹ ofin, lo fa a ti ijọba fi n fọwọ rọ wọn sẹyin, bo tilẹ jẹ pe pupọ awọn oloṣelu ati oṣiṣẹ ijọba ni wọn n de ọdọ wọn lati wa iranlọwọ.
O kọminu wi pe awọn babanla wọn ko ronu lati fi orukọ silẹ labẹ ijọba, eyi to l'awọn ko le laju silẹ mọ, ki wọn maa fi ẹtọ wọn dun wọn.
Bẹẹ lo sọ pe ohun to maa n ba wọn lọkan jẹ pupọ ni pe gbogbo ẹni ti wọn ba ti ka oogun buruku tabi iwa adojutini lọwọ wọn ni wọn maa n pe ni Babalawo, to si lawọn ṣetan lati dẹkun gbogbo rẹ.
Siwaju sii lo kọminu wi pe pupọ awọn ọmọ kaarọ-o-jiire ni wọn ko mọ iyatọ to wa laaarin Babalawo, Elewe-Ọmọ, Oniṣegun Ibilẹ, Adahunṣe, Baba Oloriṣa ati Iya Oloriṣa, eyi to sọ pe iyatọ wa laaarin gbogbo wọn, bo tilẹ jẹ pe abẹ iṣẹṣe ni wọn sa si, nitori pe iṣẹ wọn fẹẹ dọgba.
“Ọkan lara awọn idi pataki ti a fi gbe eto yii kalẹ ni lati la awọn eeyan lọyẹ nipa 'Ẹni ti a jẹ, ati ohun ti a n ṣe laaarin awujọ wa'. A ni ojuṣe lati yi erongba awọn eeyan nipa wa pada, ka yi igbagbọ awọn eeyan ati iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n gbọ nipa Babalawo pada si rere."
“Ọdun 2019 la fi orukọ yii silẹ labẹ ofin nipasẹ ẹni to jẹ Oluwo Onifa Ẹgba lonii, Oloye Ifagbeminiyi Atanda Baoku.”
O wa rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ takuntakun gbe orukọ ẹgbẹ naa larugẹ, ki ijọba le fun wọn ni ọlude ti wọn n beere fun lati ọjọ pipẹ.
Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ; Olubara tilu Ibara, Ọba Jacob Ọmọlade; Alawọ Erin ilu Ẹgba, Oloye Nurudeen Ọlalẹyẹ to jẹ aṣoju awọn Babalawo lọdọ ijọba ipinlẹ Ogun atawọn agba oloye lo wa nibi eto yii.
Awọn ọga agba ileeṣẹ eleto aabo So Safe, Sifu Difẹnsi, PCRC, Amọtẹkun ati aṣoju ijọba ipinlẹ Ogun lọrọ eto aabo ko gbẹyin nibi eto naa.
No comments:
Post a Comment