Ọkan lara awọn to fi ara kaaṣa ikọlu to waye laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ati ti Kẹkẹ Maruwa lagbegbe Iju-Fagba, Agege nipinlẹ Eko lọjọ Aje, Mọnde ana, Ọgbẹni Rasheed Ọlabọde ti sọ pe irọ nla loun pa fawọn akọroyin ayelujara ipinlẹ naa.
Bẹ o ba gbagbe, laaarọ ana ni awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ti Lagos Parks and Garages Management Committee, ti wọn wa labẹ Alaaji Musiliu Akinsanya iyẹn MC Olúọmọ ati awọn ọmọ ẹgbẹ oni Maruwa ti wọn wa labẹ Alaaji Azeez Abiọla ti ọpọ awọn eeyan mọ si Istijabah koju ija sira wọn.
Nibi ikọlu yii la gbọ pe wọn ti ba ọpọ dukia jẹ, ti wọn si tun dana sun Maruwa Rasheed Ọlabọde, iyẹn ni nnkan bi agogo meje aabọ aarọ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, a mu iroyin naa wa fun un yin wi pe Ọlabọde fẹsun kan awọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ wi pe awọn lo wa nidi ikọlu ọhun, ti wọn si dana sun Maruwa oun.
Ọsan ana ni ọkunrin naa tun bawọn akọroyin ori ayelujara, iyẹn Bloggers ti wọn fi ilu Eko ṣe ibugbe sọrọ, to sì jẹ́ ko ye wọn pe awọn ọmọ eyin Istijabah lo wa dana sun Maruwa oun, kii ṣe awọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ.
A gbọ pe ọrọ ti Ọlabọde bawọn akọroyin ori ayelujara naa sọ da ọpọlọpọ wahala silẹ, eyi ti wọn lo jẹ k'awọn eeyan bẹrẹ sii jẹ ko mọ ijiya to wa ninu irọ pipa.
Eyi ni wọn lo jẹ ko sọrọ sita, to si sọ idi to fi purọ naa.
Nigba to n sọrọ, o sọ pe ibọn l'awọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ gbe soun lori, koun to maa ba awọn akọroyin naa sọrọ, ati pe irọ to jinna si otitọ loun pa sita.
Ọlabọde ni ẹri ọkan ko jẹ koun gbadun latigba toun ti bawọn akọroyin naa sọrọ, ati pe gẹgẹ bi Musulumi ododo, ati nitori inu aawẹ tawọn wa, oun ni lati sọ otitọ.
O tẹsiwaju pe lẹyin toun ti kọkọ sọrọ laaarọ, ṣe l'awọn ọmọ ẹyin MC Olúọmọ wa ba oun, pẹlu ileri wi pe wọn yoo ra Kẹkẹ Maruwa miran foun, ati pe oun ni lati b'awọn akọroyin ori ayelujara sọrọ, koun si sọ nnkan ti ko jẹ otitọ.
Siwaju sii lo rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ọmọ Naijiria fun irọ toun pa, ati pe idunkoko ti wọn ṣe foun lo fa a. O ni ibọn ni wọn gbe sori lori, pẹlu ileri wi pe wọn yoo ra Kẹkẹ Maruwa miran foun.
Bẹẹ lo ṣe ileri wi pe oun ko tun jẹ purọ miran mọ, ni ko si bo tilẹ wu ko ri.
No comments:
Post a Comment