Afaimọ ki wahala ẹgbẹ onimọto ati Maruwa l'Ekoo ma gbọna miran yọ bi ijọba ko ba wa nnkan ṣe si i - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 25, 2022

Afaimọ ki wahala ẹgbẹ onimọto ati Maruwa l'Ekoo ma gbọna miran yọ bi ijọba ko ba wa nnkan ṣe si i


Adisa Awoyale

Ayafi bi ijọba ipinlẹ Eko ba gbe igbesẹ to yẹ lati pana wahala to n waye laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ti wọn wa lẹyin Alaaji Musiliu Akinsanya ti ọpọ awọn eeyan mọ si MC Oluọmọ ati ti ẹgbẹ awọn oni maruwa, Tricycles Owners and Operators Association of Nigerians to wa labẹ akoso Alaaji Abiọla ti ọpọ tun mọ si Istijabah, wahala naa yoo tubọ maa fi ojoojumọ tapa si ofin ati ilana gbigbe ilu Eko.
 
Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni wahala ati adojukọ ti n waye laaarin awọn ọmọ ẹyin MC Oluọmọ ati Istijabah, eyi to jẹ pe bi wọn ṣe n dana sun mọto ati dukia naa ni wọn n ṣe awọn eeyan leṣe, iyẹn lagbegbe Meiran, Ẹkọrọ, Abule Ẹgba ati Kọla.
 
A gbọ pe awọn ọmọ ẹyin MC Oluọmọ ti wọn n dide lati dana iya f'awọn ọmọ ẹyin Istijabah to n ṣakoso awọn awakọ maruwa nipinlẹ Eko.
 
Ni aarọ kutu ana tii ṣe ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe awọn ọmọ ẹyin MC Oluọmọ tun lọ kọlu awọn ibudokọ bi i Ayọbọ, Maigida, Iṣhẹfun, Amule, Oluwaga, Ipaja, Ikọla, Baruwa, Gate ati Ẹgbẹda pẹlu erongba lati gba awọn garaaji naa.
 
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ, a gbọ pe nipasẹ iranlọwọ awọn ọlọpaa ẹkun Ayọbọ ni wọn fi lọ da wahala naa silẹ.
 
Wọn ni ṣe ni wọn fẹsun kan gbogbo aọn awakọ maruwa lawọn agbegbe yii ni wọn n da wahala silẹ kaakiri, eyi ti a gbọ pe ko ri bẹẹ.
 
 
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lakoko yii, wọn ni awọn ọmọ ẹyin Alaaji Akinsanya ti gbakoso agbegbe naa, to si jẹ pe nigba t'awọn ọlọpaa RRS yoo debẹ, awọn awakọ maruwa ni wọn bẹrẹ sii ko, lati fun awọn ọmọ ẹyin MC Oluọmọ laaye lati gba awọn garaaji ọhun.

A fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa gbe ọrọ yii yẹwo lati gbe igbesẹ lori iwa ti DPO Ayọbọ naa hu, ki iru ẹ ma tun le ṣẹlẹ mọ lọjọ iwaju.
 
Eyi to ṣe pataki julọ ni pe ko gbọdọ sẹni ti yoo dori alaafia ipinlẹ Eko kodo. Ayọbọ ati agbegbe rẹ ni wahala yii ti waye lanaa, o le jẹ ibomiran ni ọla, ko sẹni to le sọ.
 
Ko sẹni to kọja ofin, a ko si gbọdọ dakẹ lori ohun to n ṣẹlẹ yii. Wahala ojoojumọ to n ṣẹlẹ yii ko ba oju mu to, ojuṣe ijọba si ni lati pe awọn igun mejeeji, iyẹn MC Oluọmọ ati Istijabah lati ba wọn yanju aawọ to ba wa laarin wọn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI