Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe owo ti ko din ni ogun miliọnu naira kalẹ fun fasiti Muhammad Kamaldeen to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara pẹlu erongba lati jẹ ki iṣẹ bẹrẹ lakọtun, ki eto ẹkọ nibẹ si le tete bẹrẹ.
Opin ọsẹ to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq ṣeleri owo naa fun idagbasoke eto ẹkọ ni fasiti naa, ati ki iṣẹ to n lọ lọwọ le tete pari nibẹ.
Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, wọn ni erongba agba musulumi to dagbere faye laipẹ yii, Sheikh Muhammad Kamaldeen al-Adaby, ẹni to tun jẹ Grand Mufty tiluu Ilọrin ni fasiti ọhun jẹ, fun idagbasoke ẹsin Isilaamu.
Sheikh Muhammad Kamaldeen al-Adaby tun ni oludasilẹ ajọ ti Ansar-ul-Islam.
Nigba to n sọrọ, sọ pe bi awọn akẹkọọ ṣe n daamu lati wọ ile-ẹkọ giga lakoko yii jẹ ohun to n kọ ni lominu, eyi to si n pe fun idasilẹ ile-ẹkọ giga aladani kaakiri orileede yii lati di alafo to ṣofo laaarin awọn akẹkọọ.
Siwaju si i ninu ọrọ rẹ nibi eto agbekalẹ eto akanṣe adura ati ẹdawo fun ajọ Muhammad Kamaldeen Education Foundation (MUKEF), eyi ti Ansarul Islam Society of Nigeria gbe kalẹ ni gbagede fasiti ọhun to wa lagbegbe Ogidi, Ilọrin jẹ ko ye gbogbo eeyan pe agbajọwọ lo n mu idagbasoke ba erongba rere.
Lara awọn to tun wa nibẹ ni Grand Kadi fidihẹ ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti Shariah, Onidajọ Abdullateef Kamaldeen; Khalifatul Adabiyyeen Sheikh AbdulQadir Kamaldeen; Turakin Ilorin ati alaga eto naa, Saliu Mustapha; igbakeji aarẹ apapọ ajọ naa, Onimọ-ẹrọ Salihu Yusuf; ati Ọnarebu Zakary Funsho Yusuf.
No comments:
Post a Comment