AbdulRazaq bura fawọn akọwe agba tuntun meje - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 20, 2022

AbdulRazaq bura fawọn akọwe agba tuntun meje


Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ipinlẹ Kwara lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti bura fawọn akọwe agba ti ko din ni meje, lati fi di awọn ipo naa to ṣofo lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin.

Yatọ si eyi, Gomina AbdulRazaq tun ṣe iṣipopada fawọn akọwe agba meji kan lẹka eto iṣejọba, to si gba wọn lamọran lati ṣiṣẹ papọ pẹlu gbogbo awọn ti yoo ṣiṣẹ labẹ akoso wọn, fun idagbasoke to lọọrin.

Awọn akọwe agba tuntun naa ni: Ibrahim Mohammed (Establishment); Yahya Mohammed (Water Resources); Sidikat Alaya (Tertiary Education); Iyabọ Dupẹ Adekẹyẹ (Environment); Umar Yakubu Jaja (Planning); Salman Suleiman (Service Welfare); ati Rebecca Bake (Social Development).

Bẹẹ, awọn meji to gba iṣipopada ni: Ọkanlawọn Musa lati Water Resources bọ si Special Duties ati Adenikẹ Ibrahim toun wa ni Social Development/Women Affairs bọ si Solid Minerals.

Siwaju si i ni AbdulRazaq tun gba awọn eeyan lamọran lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn to tun jẹ ọga wọn lẹka eto oṣelu, ki ohun ti wọn n foju sọna fun ninu idagbasoke le wa si imuṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI