Aarẹ ile igbimọ aṣofin lorileede yii, Ọmọwe Ahmed Lawal; Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ati Sẹnetọ to n ṣoju ekun Ariwa Kwara, Sadiq Suleiman Umar ni wọn ti joye tuntun niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
Ohun ti a gbọ pe awọn ti wọn ri ipa rere tawọn eeyan naa n ko lawujọ ni wọn we lawaani oye tuntun fun wọn niluu Kaiama, Ilórin, ipinlẹ naa.
Oye Magayaki tiluu Kaiama la gbọ pe wọn fi Gomina AbdulRazaq ati Lawal jẹ, nigba ti wọn fi Sadiq jẹ Dan-Amar, eyi to tunmọ si Ayanfẹ Ọmọọba Kaiama.
Ana ti i ṣe Aiku, Sannde la gbọ pe ayẹyẹ wiwe lawaani oye tuntun naa waye niluu Kaiama, ipinlẹ Kwara, nibi ti ẹsẹ ko ti gbero rara.
No comments:
Post a Comment