Awọn amookunṣeka kan tun ti ran bàbá àgbàlagbà, ẹni ọdún marundinlaadọrun (85), Alagba Jimọh Ọladiran lọ s'ọrun aremabọ nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Ọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé ọsẹ to kọjá yìí la gbọ pé wọn tán Jimọh lọ sí inú igbó kan to wa nijọba ibilẹ Abẹokuta North, ipinlẹ naa.
A gbọ pé igi ni wọn fọ mọ baba naa lori, titi to fi jáde laye, ti wọn sì lọ ju oku rẹ seti odò, ìyẹn ni Abule kan ti wọn pe ni Aṣipa.
Sulaiman Ọladiran to jẹ akọbi oloogbe nigba to n ba AWIKONKO sọrọ, o jẹ ko ye wa pe abule Aṣipa ni baba àwọn dagbere ni nnkan bi agogo mẹwàá aarọ, ọjọ Àbámẹ́ta, tii ṣe Satide ọsẹ to kọjá yìí, ìyẹn ọjọ kẹwàá, oṣù kẹta ti a wa yii.
O tẹsiwaju pé saara ni baba oun sọ pé òun pẹlu aburo rẹ fẹẹ lọ ṣe, ṣugbọn ti ko pada sile latigba naa.
Ninu ọrọ rẹ, o ṣàlàyé pé "Nnkan bi agogo mẹwàá aarọ ni baba mi dagbere fún mi pé àwọn fẹẹ lọ sí abúlé Aṣipa. Wọn ní awọn ati aburo awọn ni wọn fẹ lọ ṣe saara níbẹ. Igba to di irọlẹ, mi o ri wọn.
"Mo wa pe ẹgbọn wa to jẹ Baálẹ̀ ilu Aṣipa yìí, Oloye Kehinde Omirinde lati ṣàlàyé fún wọn. Awọn ni wọn sọ pe ka ṣi ni sùúrù di ọjọ keji ka tó mọ igbesẹ ti a máa gbé lati wa wọn lọ.
"Nigba ti a ko ri wọn di agogo mejila ọjọ keji, mo tun pé Baálẹ̀ yìí, wọn wà sọ pé a kò tún gbọdọ duro mọ. Bi wọn ṣe tẹle wa lẹyin niyẹn, ti a fi jọ lọ. Igba ti a de'bẹ, a pade Ibrahim Mufatiu toun pẹlu baba wa jọ lọ. Oun lo sọ pé ka ni sùúrù, nitori pe abule keji ni baba wa lọ, ati pé wọn máa tóo de.
"O loun n bọ lati lọ wo baba wa wa, tó sì gba ọna isalẹ ti odò wa. Awọn to wa níbẹ ti a jọ n sọrọ lọwọ, a ti ṣakiyesi pe ọkan wọn kò balẹ, wọn ti n gbọn. Ibẹ ni ara ti n fu mi.
"Ibi ti a ti n sọrọ lọwọ ni Ibrahim Mufatiu tun ti pada de, ti a sì béèrè baba wa lọwọ, ṣugbọn to tun sọ pe ka fi ara balẹ, a máa rí baba wa. Loju ẹsẹ lo tun ti sọ pé ká ṣe oun jẹjẹ tabi pe ka pa oun. A sọ fún ùn pe ọrọ ti a n beere kọ lo n sọ, ko juwe ibi ti baba wa fún wa.
"Bó ṣe rìn sẹyìn, tó sì salọ niyẹn. Loju ẹsẹ l'awọn yòókù ẹ ti sare lọ ko ada ati nnkan ìjà oloro, ti wọn fi n le wa. Ibi ti a ti n salọ lati pade awọn ọlọpaa OPMESA lagbegbe abule Ọpẹji, awọn ni wọn daabobo wa.
"Iṣẹ kafinta ni baba wa n ṣe ni Ọbantoko. Aarọ ọjọ keji, to jẹ Mọnde ni Ibrahim Mufatiu mu awọn ọlọpaa lọ sí etí odò tí wọn pa baba mi si. O jẹ nnkan ìbànújẹ fún mi."
Baálẹ̀ ilu Aṣipa, Oloye Mọshood Kẹhinde Omirinde nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, o sọ pé "A fi ki awọn ọmọ Naijiria gba mi, nitori pe mi o mọ àwọn èèyàn yìí rí, àkóbá nla ni wọn fẹẹ fi ṣe fún mi.
"Mi o mọ ibi ti wọn ti ri ẹrọ ibanisọrọ mi, ti wọn fi pe mi pe awọn fẹẹ da oko, mọ sọ pé kò saaye. Ibrahim Mufatiu ati baba ẹ, Aafa Mufatiu ni wọn pe mi. Ọjọ kẹta lẹyin ẹ ni wọn lọ pe ẹgbọn mi, Alagba Jimọh Ọladiran wa lati Ọbantoko.
"Ẹgbọn mi yii ni wọn sọ pé kí n jẹ ki wọn da oko naa. Mo jẹ ko ye wọn pe awọn ẹbi gbọdọ mọ si, ati pé lẹyin ti awọn ẹbi ba ti da si, loun yóò to gba wọn láàyè. Igba to tun ya ni wọn sọ pé awọn fẹẹ ṣe saara, atipe awọn yóò pe mi bi akoko ba to.
"Aburo baba mi ni baba ti won pa yii, ṣugbọn mi o mọ bi wọn ṣe tán mọ awọn to pa wọn yìí. Wọn sọ pe idile iya lọ pa awọn pọ, ṣugbọn mi o le dahun ẹ. Lọjọ ti wọn pe mi pe awọn fẹẹ lọ ṣe saara yìí, ọkan mi ko lọ, idi ree ti mi o fi tẹle wọn lọ.
"Kani aburo baba mi pe mi pe awọn fẹẹ tẹle wọn lọ ní, máa sọ pé wọn kò gbọdọ lọ, ṣugbọn wọn kò pé mi. Igba ti mo máa gbọ ni awọn aburo mi bẹrẹ síi pé mi pe awọn ko rí baba wọn. Kí n ma fa ọrọ gun, oku baba la pada rí o. O ṣi n jẹ iyalẹnu fún mi."
No comments:
Post a Comment