Ọwọ tẹ awakọ taisi to n da idọti kaakiri ipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 14, 2022

Ọwọ tẹ awakọ taisi to n da idọti kaakiri ipinlẹ Kwara


Ọwọ ijọba ipinlẹ Kwara ti tẹ baba agbalagba kan ti wọn loun naa wa lara awọn to n ko idọti ba ilu Ilọrin, pàápàá ipinlẹ Kwara lapapọ.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto ayika nipinlẹ náà, Ọnarebu Abọsẹde Ọlaitan Buraimọ la gbọ pé àṣírí baba naa ti sí lọwọ lakoko to n da idọti káàkiri igboro.

Níbẹ lo si ti pariwo sita wí pé alaigbọran ni pupọ ninu araalu nitori iwa aigbọran wọn.


Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yìí ni ìjọba Kwara bẹrẹ eto imọtoto ayika ati agbegbe nipinlẹ náà, ti wọn sì ṣètò ibi tàwọn araalu yóò máa dá idọti wọn sì.

Ṣugbọn nígbà tó n káàkiri lati ṣe abẹwo s'awọn agbegbe ti ijoba gbe awọn ohun elo idalẹnu si, ni o ti ṣalabapade baba naa pẹlu mọto rẹ tó kún fún ọpọlọpọ idọti.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI