Ọwọ ṣinkun ajọ EFCC tẹ afurasi 'ọmọ Yahoo' mejila l'Ẹnugu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 21, 2022

Ọwọ ṣinkun ajọ EFCC tẹ afurasi 'ọmọ Yahoo' mejila l'Ẹnugu


Ọwọ ṣinkun ajọ EFCC, ẹka ti Ẹnugu ti tẹ awọn afurasi gbajuẹ ori ẹrọ ayelujara mejila kan ni Nsukka ati Emene nipinlẹ Ẹnugu.

Ọwọ ba wọn lọjọ kẹẹdogun oṣu kẹta, ọdun 2022 ninu iwọde ti ajọ naa ṣe. 

Awọn mejila ti igbagbọ wa pe wọn lọwọ ninu ṣiṣe gbajuẹ ori ẹrọ ayelujara ni: Chinaza Onyekwelu; David Sharon; Igwenagu Chimezie; Nnachi Collins; Noble Nwodo ati Okoye Ebuka.


Awọn to ku ni: Onaga Divine; Richie Samson; Ugwu Chideru; Victor Sopuluchi; Nwajie Chidubem Eric ati Nnamani Chukwuebuka. 

Ọwọ ba wọn lẹyin olobo kan to ta ajọ EFCC lori iṣẹ buruku tawọn afurasi ọhun n ṣe. 

Fun ẹkunrẹrẹ alaye lori iroyin yii at'awọn iroyin miiran, ẹ wo ori itakun ẹrọ ayelujara EFCC lori www.efccnigeria.org.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI