Awọn ẹgbẹ kan to jẹ ti oṣelu, eyi ti wọn pe ara wọn ni Kwara Political Front (KPF) ti sọ pe wahala kan to bẹ silẹ n'ijọba ibilẹ Ariwa Kwara ti sọ pe ko ṣẹyin gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Sẹnetọ Bukọla Saraki.
Ẹgbẹ naa wa n rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorileede yii lati pe Sẹnetọ Bukọla Saraki, ẹni to tun jẹ aarẹ ana fun ile igbimọ aṣofin orileede yii, ki wọn si fi ọrọ wa a lẹnu wo lati ohun to mọ nipa ẹ.
Wọn ni yatọ si pe wọn pe Saraki lati fi ọrọ wa a lẹnu wo, wọn tun nilo lati maa ṣọ gbogbo irin ẹsẹ rẹ lasiko yii nitori pe o lọwọ si wahala naa.
Nigba to n sọrọ ninu atẹjade kan to gbe jade, Aarẹ ẹgbẹ KPF naam Alaaji Abdullahi Mohammad, sọ pe ohun to kan awọ ninu ọrọ wahala naa ni aṣiri ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ṣẹṣẹ tu sita, to si ni eyi gan-an ti fi han pe awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ.
No comments:
Post a Comment