Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ba kọmiṣanna tẹlẹri fun ọrọ eto ẹkọ nipinlẹ naa, Onimọ-ẹrọ Musa Yeketi kẹdun iku ọmọ rẹ, Onimọ-ẹrọ Nafiu, ẹni to jade laye laipẹ yii.
Yeketi, ẹni to tun jẹ ọkan pataki lara awọn agba lẹgbẹ oṣelu APC la gbọ pe o padanu ọmọ rẹ yii lẹyin aisan rampẹ.
Ninu atẹjade ti gomina gbe jade lalẹ ana, ti i ṣe Tuside lo ti ṣapejuwe iku naa gẹgẹ bi ajalu ati eyi to ba ni lọkan jẹ gidigidi, to si n gba agba oṣelu naa lamọran lati mu ọkan le.
No comments:
Post a Comment