Kọ́milẹ́kọ̀ọ́: Èyí ni orúkọ àwọn ẹranko àgbáyé ni èdè òyìnbó àti Yorùbá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 7, 2022

Kọ́milẹ́kọ̀ọ́: Èyí ni orúkọ àwọn ẹranko àgbáyé ni èdè òyìnbó àti Yorùbá


Ọpọ awọn eeyan ni wọn mọ orukọ ẹyẹ ati ẹranko lede Oyinbo, ṣugbọn ti wọn ko mọ itumọ wọn lede Yoruba to jẹ abinibi wọn.

Bakan naa lawọn eeyan tun mọ orukọ ẹranko ati ẹyẹ lede Yoruba, ṣugbọn ti wọn ko mọ orukọ ti wọn n pe wọn lede Oyinbo.

Eyi lo jẹ ka mu diẹ fun un yin lati mọ orukọ awọn ẹranko ati ẹyẹ lede Oyinbo ati Yoruba. Awọn naa niwọnyi:

Aaka = Hedgehog

Àgbọ̀nrín = Deer

Agẹmọ, ògà = Chameleon

Àgódóńgbò = Colt

Àgùnfọn = Giraffe 🦒

Àkekè = Scorpion 🦂

Àkókó = Wood pecker

Akò = Grey Heron

Àparò = Bushfowl

Àwòdì, Àṣá = Kite

Ẹfọ̀n = Buffalo 🐃

Ẹ̀ga = Weaver

Erè, Òjòlá = Python

Erin = Elephant 🐘

Erinmi = Hippopotamus 🦛

Ẹtà = civet cat 🐈

Ẹtù, Awó = Guinea fowl

Etu, Èsúró = Duiker

Ewúrẹ́ = Goat 🐐

Ràkúnmí = camel 🐪

Ìbákà = Canary bird

Ìgalà = Bushbuck

Ìjàpá, Ahun, Alábahun = Tortoise 🐢

Ìnọ̀kí = Baboon or Mandrill

Ìràwò = Beetle 🪲

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ = Fox 🦊

Kìnìún = Lion 🦁

Lámilámi = Dragonfly

Ọ̀fàfà = Tree hyrax

Ọ̀bọ = Monkey 🐒

Ológbò = Cat 😸

Ọmọ-ńlé = Gecko Lizard/Wall Gecko

Òtòlò = Waterbuck

Òwìwí = Owl 🦉

Ọ̀yà = Cane Rat/Grasscutter

Pẹ́pẹ́yẹ = Duck 🦆

Yànmùyánmú, ẹ̀fọn = Mosquito 🦟

Eranko bí ìmàdò/Àgbánréré = Rhinoceros 🦏

Ẹkùn/Ògìdán = Tiger 🐅

Àmọ̀tẹ́kùn = Leopard 🐆

Erinmi/Erinmilókun = Hippopotamus 🦛


Ìmàdò = Wild boar 🐗

Ìkokò = Hyena/Hyaena

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ = Donkey 🐴

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abìlà = Zebra 🦓

Ìjímèrè = Brown Monkey 🐵

Egbin/Ẹtu/Olube/Èsúró = Antelope

Ọ̀wàwà = Cheetah 🐆

Ọṣà = Chimpanzee

Ọká = Gabon Viper

Sèbé = Cobra 🐍

Awọ́nríwọ́n = Alligator 🐊

Àléégbà = Monitor Lizard 🦎

Igún, Gúnnugún, Gúrugú = Vulture

Ológìrì = Palm bird

Àrígiṣẹ́gi = Wood-Carrier

Ọ̀kín = Peacock 🦚

Ọ̀kẹ́rẹ́ = Squirrel 🐿️

Òkété = Pouch Rat 🐁

Èdú = Wild Goat

Àkúrákudà = Shark 🦈

Ekòló = Earthworm 🪱

Ẹyẹ-Orin = Songbird

Àparò = Partridge

Ìbákàsìẹ́ = Ass

Ẹyẹ-Ofu = Pelican

Ọsìn = Water Bird

Yanja-yanja = Sea Bird

Àdàbà = Dove

Paramọ́lẹ̀ = Viper

Pẹju-pẹju = Seagulls

Sọmídọlọ́tí/Olóyọ́ = Yellow-haired Monkey

Ẹyẹ-Iwo = Raven

Ìṣáwùrú = Fresh-water Snail

Ìgbín/Aginniṣọ = Snail 🐌

Ẹdun = Ape 🦧

Aláǹgba = Lizard 🦎

Alakasa = Lobster

Erè = African rock python

Ẹlẹ́dẹ̀-Igbó = Boar 🐗

Elégbèdè = Chimpanzee

Ojòlá = African rock Python

Kọ̀ǹkọ́ = frog

Ọ̀pọ̀lọ́ = Toad 🐸

Eégbọn = Tick/flee 

Akàn = Crab 🦀

Oriri = Wild pigeon 🐦

Òòrẹ̀, Èèrẹ̀, Òjìgbọ̀n = Porcupine

Tanpẹ́pẹ́ = Blank-ants

Ọ̀kùnrùn = Millipede

Ajá-Ọdẹ = Hound

Lékeléke = Cattle-egret

Ọgòǹgò = Ostrich

Ikán, Ìkamùdù = White ant/Termite

Idi = Eagle 🦅

Oyin = Bee 🐝

Eṣinṣin/Eṣin = Housefly

Kòkòrò-Ojúọtí = Gnats

Ẹ̀lírí = Mouse 🐀

Abóníléjọpọ́n = Red-ants

Iná-Orí = Lice


Ìdun = Bedbugs

Alápàńdẹ̀dẹ̀ = Swallow

Irù, Eṣinṣin-ńlá = Gadfly

Akátá/Ajáko = Jackal

Ọ̀ọ̀nì = Crocodile 🐊

Eja-odò = Fresh water fish 🐠

Àfèrègbèjò/ Àfè-ìmọ̀jò = A species of rat

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI