Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Ẹnugu ti tẹ gbajugbaja oludasilẹ ṣọọṣi kan nipinlẹ Ẹnugu, Pasitọ Kelechi Vitalis Anozie, lori ẹsun jibiti.
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ ati iwadii tilẹ Amẹrika, iyẹn US Federal Bureau of Investigation (FBI) la gbọ pe wọn kede Anozie gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa lori ẹsun jibiti ati gbajuẹ ti wọn fi kan an.
Oludasilẹ ṣọọṣi Praying City, iyẹn Praying City Church to wa nilu Owerri, ipinlẹ Imo ni wọn pe Anozie, ẹni ti wọn sọ pe ogbologbo ni ninu ka lu jibiti.
Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun 2022 ni iroyin fi to wa leti wi pe ọwọ EFCC tẹ Anozie, lẹyin ti iwadii fidi rẹ mulẹ wi pe o lọwọ si iwa jibiti ori ayelujara.
Awọn mẹrin miran ti ọwọ tun tẹ, iyẹn awọn ti a gbọ pe wọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu Anozie ni Valentine Iro, Ekene Ekechukwu (alias Ogedi Power), Bright Azubuike (alias Bright Bauer Azubuike) ati Ifeanyi Junior.
Wọn ni ẹnikan ti wọn pe ni F.F, ẹni to n gbe niluu Illinois, United States, ni wọn lu ni jibiti $135,800 owo dọla, ti wọn si tun lu ẹlomiran ni jibiti $47,000 owo dọla.
No comments:
Post a Comment