Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Kwara Gentlemen’s Club ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Sẹnetọ Bukọla Saraki ati Abdulfatah Ahmẹd lakooko ti wọn wa ni iṣakoso gomina ipinlẹ Kwara lori ọrọ omi.
Wọn ni lakooko ijọba awọn mejeeji yii, owo ti ko din ni biliọnu mẹfa naira ni wọn lawọn fi ṣe atunṣe omi ero igbalode, eyi ti wọn sọ pe ko si otitọ kankan níbẹ.
Siwaju si i ni wọn jẹ ko di mimọ pe pẹlu gbogbo owo ti wọn lawọn ti na yii, ko si omi ẹrọ igbalode kankan to yọ kaakiri ile to wa nilu Ilọrin.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin naa jade sita wi pe ijọba Saraki ati Abdulfatah na owo ti ko din ni biliọnu mẹfa naira lati gi ṣe omi ẹrọ igbalode fawọn araalu Ilọrin, nipa ṣiṣe atunṣe gbogbo awọn ọpa omi to ti bajẹ.
Ẹgbẹ naa wa n rawọ ẹbẹ wi pe ki ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tọpinpin ohun ti wọn fi owo naa ṣe, nitori ti awọn ko ni igbagbọ wi pe ohun ti wọn lawọn fi ṣe ni wọn fi ṣe.
No comments:
Post a Comment