Awujakọ tilu Ijakọ Orile nijọba ibilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun, Ọba Matthew Alabi Ewedairo, ti rawọ ẹbẹ s'ijoba orileede Naijiria, paapaa ijọba ipinlẹ naa lati gba oun lọwọ awọn kan to sọ pe wọn n fi iku wa oun kaakiri lasiko yii, to si ni ẹmi oun ati awọn araale oun wa ninu ewu nla.
Ọba Alabi Ewedairo lo pariwo yii sita laipẹ yii niluu Abẹokuta, lakoko to n bawọn akọroyin sọrọ, to si ni gbogbo ọna lawọn kan to pe ni ajagungbale n wa lati ri i pe oun jade laye.
Kabiyesi, naa nigba to n sọrọ sọ pe lati ọdun 2012 ni wahala naa ti bẹrẹ, ko to di pe oun gba ade, ṣugbọn to ni wọn ko dẹyin lẹyin oun titi di asiko yii. O ni Ọba Awujako ana lo foun jẹ Baalẹ gẹgẹ bi ẹni ti ipo naa tọ si, ṣugbọn to ni ko tẹ awọn kan lọrun, ti wọn fi dide ogun.
Siwaju sii lo ṣalaye pe lẹyin ti Ọba naa waja ni wọn sọ pe oun ni ipo ọba kan, to si lawọn kan tun dide wi pe oun ko nii jẹ ọba naa, ati pe wọn tun n sọ pe boun ba lo oṣu mẹta lori ipo lai papoda, lawọn ṣẹṣẹ mọ pe lotitọ loun jẹ ọba.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ko tii ju oṣu mẹta ti mo jẹ ọba ni wọn dena de mi lati pa mi danu, ṣugbọn ti mo raaye sa mọ wọn lọwọ. Awọn ọlọpaa Imaṣayi ni wọn ba mi gbe mọto mi kuro nibi ti wọn ti da mi duro.
“Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2021 to kọja ni mo gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun gẹgẹ bi ọba. Oṣu kẹta lẹyin rẹ ni wọn dena de mi.”
Kabiyesi naa tun ṣalaye siwaju pe eyi to n ya oun lẹnu julọ ni bi awọn kan toun ko mọ ṣe dide lati pe ẹjọ lorukọ oun, eyi ti wọn fi n dunkoko mọ awọn araalu niwaju ile-ẹjọ giga apapọ to wa nilu Abẹokuta.
Ẹjọ naa to pe nọmba rẹ ni FHC/AB/FHP/178/2, lo sọ pe gbogbo awọn mẹtẹẹta ti orukọ wọn farahan gẹgẹ bi olupẹjọ loun ko mọ ri, to si loun ko tun mọ agbẹjọro to pe ẹjọ naa ri nibikankan.
“Mi o mọ Oseni Ajayi, Yusuf Ajibawo, ati Akanni Ewedairo-Lawal ti orukọ wọn wa ninu iwe ipẹjọ yii ri, a ko mọ wọn ri niluu Ijakọ, bẹẹ si ni wọn ko ni ẹtọ kankan lati pe ẹjọ fun ilu Ijakọ Orile ati gbogbo awọn agbegbe to wa labẹ ẹ bii Ajibawo, Afami, Abule Ọkẹ, Maria ati awọn Aga lapapọ, nitori pe a ko mọ wọn ri.
“Gbogbo awọn orukọ ti wọn fẹsun kan ninu iwe ẹjọ yii ni mi o mọ ri, ohun ti mo ṣakiyesi ni wi pe awọn ajagungbale ni wọn wa nidi iwe ipẹjọ yii, nitori pe wọn ti ri gbogbo ogo ati nnkan amuṣọrọ to wa nilu Ijakọ-Orile atawọn agbegbe to wa nibẹ.”
Lakotan, o wa rawọ ẹbẹ sijọba Gomina Dapọ Abiọdun lati tete dide iranlọwọ foun ko to di pe wọn ṣeku pa oun gẹgẹ bi wọn ṣe ṣeku pa Ọba Agodo loṣu kin-in-ni, ọdun yii.
No comments:
Post a Comment