Aye o! Wọn da ẹjọ iku fun pasitọ to fẹẹ ṣoogun owo l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 17, 2022

Aye o! Wọn da ẹjọ iku fun pasitọ to fẹẹ ṣoogun owo l'Ekoo


Ile ẹjọ giga kan to wa lagbegbe Tafawa balewa Square nipinlẹ Ekoo, l'Ọjọru, Wẹside ti da ẹjọ iku fun Fatai Afọbajẹ, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan lori ẹsun ipaniyan, ati gige oku naa wẹlẹwẹlẹ.
 
Onidajọ Modupẹ Nicol-Clay lo da ẹjọ naa fun Fatai, ẹni ti wọn sọ pe iṣẹ pasitọ lo yan laayo.
 
O ni Fatai jẹbi ẹsun igbimọ-paniyan, ati ipaniyan, to si ni ijiya ninu.
 
A gbọ pe lọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2015 ni Fatai ṣeku pa ẹnikan ti wọn pe ni Rafiu Sulaiman, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, to si ge ori, ifun, ikọfun, woropọn ati ọwọ rẹ mejeeji salọ, pẹlu erongba lati fi ṣoogun owo lagbegbe Magbọn, Badagry nipinlẹ Eko
 
Ẹsun naa ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran ati ipaniyan tipinlẹ Eko ti abala 221 ati 231.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI