Awọn to le ni idaji miliọnu ni wọn ko tii gba kaadi idibo wọn n'ipinlẹ Ogun - Ajọ INEC pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 23, 2022

Awọn to le ni idaji miliọnu ni wọn ko tii gba kaadi idibo wọn n'ipinlẹ Ogun - Ajọ INEC pariwo sita


Ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun, iyẹn National Independent Electoral Commission, INEC ti pariwo sita wi pe awọn to le ni idaji miliọnu ni wọn ko ti i gba kaadi idibo alalopẹ, eyi ti wọn pe ni Permanent Voters Card, PVC wọn.

Wọn ni iye awọn ti wọn ko ti i wa gba awọn kaadi idibo naa jẹ 651,551, iyẹn lati ọdun 2011 ti wọn ti fi orukọ wọn silẹ fun un, ti wọn si n rọ gbogbo awọn ti wọn ko ti i gba lati ri i pe wọn tete jade lọ gba a.

Alaga ajọ INEC tuntun, Ọgbẹni Niyi Ijalaye lo sọ eyi di mimọ nibi ipade awọn oniroyin to ṣe pẹlu awọn akọroyin ipinlẹ Ogun niluu Abẹokuta lonii, Ọjọru, Wẹsidee.


Ọgbẹni Ijalaye je ko di mimọ pe ni akọsilẹ ti ajọ naa ṣe lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta, ọdun 2022, ọpọ awọn to ti fi orukọsilẹ ni wọn ko ti i gba kaadi wọn, to si ni awọn oludibo ni wọn l'aṣẹ lati fi aṣaaju sipo.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
"Ẹyin olukopa, mo fẹẹ ran an yin leti wi pe kaadi idibo alalopẹ ti wa nilẹ fun gbigba kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Ogun fun gbogbo awọn ti wọn ko ti i gba. Ninu akọsilẹ ti a ṣe, kaadi idibo alalopẹ to le ni miliọnu kan 1,126,247 la gbe jade.

"Titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta, ọdun 2022, a ṣi ni 651,551 kaadi idibo ti awọn oludibo ko ti i wa gba. ẹ jẹ ki n fi eyi sọ ododo wi pe kaadi idibo alalopẹ yii kii bajẹ, ko sigba ti ko wulo, paapaa lakoko ti idibo ba de.

"Fun idi eyi, ẹ jẹ ka gba awọn eeyan wa lamọran lati jade lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn, dipo ki wọn tun lọ fi orukọ silẹ lẹẹkeji."

Siwaju si i ni alaga INEC naa, Ọgbẹni Ijalaye tun gba gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu kaakiri ipinlẹ naa lamọran, lati sọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati sọ fun awọn eeyan wọn ti wọn ko ba ti i gba kaadi idibo wọn lati tete lọ gba a ko to to asiko ti ko ni saaye mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI