Fun bi ọpọlọpọ wakati ni nnkan ko fi rọgbọ lagbegbe Badore to wa ni Iju Odo, ijọba ibilẹ Okitipupa, ipinlẹ Ondo lopin ọsẹ to kọja yii, lakoko ti ẹyẹ abami kan jabọ lati oju ofurufu.
A gbọ pe ibi ti ẹyẹ naa ti wọn lo dabi ẹyẹ awodi ti n fo kaakiri lo ti jabọ silẹ lojiji, to si n pariwo. Ariwo yii, to si n pọkaka iku ni wọn lo mu kawọn to wa nibẹ sare lọ wo o.
Wọn ni ṣe ni pupọ awọn to wa nibẹ kọkọ na papa bora nigba ti wọn ri ẹyẹ abami to jabọ lojiji yii, ṣugbọn ti awọn ti wọn ni ọkan si lọ sibẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.
Ko si nnkan to n jẹ ki ọrọ ẹyẹ naa maa jẹ kayeefi, bi ko ṣe pe wọn tun ba orukọ abami kan ti wọn kọ ọrọ ajoji kan si lara lese rẹ, ti ko si lee jabọ.
Lara awọn to sọrọ nipa iṣẹlẹ naa ṣalaye awọn ko ri iru nnkan bẹẹ ri laye awọn, bo ilẹ jẹ pe awọn kan maa n gbọ ni. Wọn ni kayeefi lo jẹ fun wọn pe ẹyẹ naa jabọ.
No comments:
Post a Comment