Awọn afurasi ọmọ 'Yahoo' mẹtalelọgbọn ha l'Ekoo ati Ẹnugu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 23, 2022

Awọn afurasi ọmọ 'Yahoo' mẹtalelọgbọn ha l'Ekoo ati Ẹnugu


Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti tẹ awọn afurasi gendekunrin mẹtalelọgbọn ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ.
 
Ipinlẹ Eko ati Ẹnugu la gbọ pe ọwọ ti tẹ gbogbo wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii.

Awọn mẹtadinlogun la gbọ pe ọwọ palaba wọn segi laaarin igboro ilu Eko, ti ọwọ si tẹ awọn yooku nipinlẹ Ẹnugu lori ẹsun gbajuẹ ti wọn fi kan wọn.

Lara awọn tọwọ tẹ l'Ekoo ni: Adefila Ayọbami Ezekiel, Anamene Somtochukwu, Nzeako Kosisochukwu Anthony, Afọlabi Ayọmide Henry, Ọlatọna Ayọdeji Ebenezer, Obioho Ikenna Raphael, Famọlayọ Fẹmi Hammed, ati Mintah-Joshua Oluwafemi.

Awọn yooku ni: Martins Victor Onuoha, Babatunde Haruna Oluwaṣeyi, Taiwo Bọlaji Kẹhinde, Ibeakolam Goodluck, Ọnaọlapọ Iyanu Samuel, Jamiu Damilọla Lawal, Adeyanju Fawaz, Adejide Samuel ati Obioho Obinna.

Wọn ni agbegbe Ọkọta nipinlẹ Eko lọwọ ti tẹ wọn lẹyin olobo kan to ta wọn wi pe awọn eeyan naa lọwọ si iwa jibiti ori ayelujara.

Mọto bọginni mẹfa, kọmputa alagbeeka ati foonu olowo iyebiye loriṣiriṣi la gbọ pe wọn gba lọwọ wọn, gẹgẹ bi Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ fun ajọ EFCC ṣe ṣalaye.

Lara awọn tọwọ tẹ l'Ẹnugu ni: Ovu Chimezie, Junior Gentle Pepple, Nwoye Paul, Ezeoke Chimelue, Innocent Kenechukwu, Tochukwu Igbonekwu, Chigozie Oguanya.

Awọn yooku ni: Nwachukwu Daniel, Charles Duru Chibuzor, Anderson Ugochukwu, Chinedu Nwasu, Obiora Martin Ugonna, Nwabueze Chidindu, Nwabueze Samuel Nnaemeka, Okechukwu Collins ati Nwabueze Benjamin Ikenna.

Uwujaren fidi rẹ mulẹ wi pe gbogbo wọn ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI