Oludije sipo sipo gomina nipinlẹ Ogun lọdun 2023, Jimi Lawal ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ Reno Ọmọkri sọ sita laipẹ yii pe iṣẹ to wa ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni lati wa wo bi nnkan ṣe n lọ nibẹ, ko si da ẹgbẹ naa ru.
Reno Ọmọkri ninu fọnran kan to gbe jade laipẹ yii lo ti fẹsun kan Jimi Lawal wi pe ṣe ni wọn ran an lati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lati wa da ẹgbẹ oṣelu PDP ru, to si n pariwo wi pe wọn ko gbọdọ gba a laaye.
Ṣugọn nigba toun naa n tako ọrọ Ọmọkri, Lawal, ẹni to jẹ oludamọran pataki fun Gomina Nasir El-Rufai sọ pe ko si ọrọ meji to maa n ti ẹnu ọkunrin naa jade, eyi to yatọ si ti alaaganna, to si ni kẹnikẹni ma ṣe gba ọrọ rẹ gbọ rara, nitori pe ko mọ ohun to n sọ.
Jimi Lawal tẹsiwaju pe oun kii ṣe igi wọrọkọ to n da ina ru, bi ko ṣe pe atunṣe loun n wa fun ipinlẹ Ogun, to si tun jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ranṣe pe oun lati wa jade du ipo gomina lebẹ asia ẹgbẹ naa.
Bakan naa lo sọ pe ọwọ ti wọn fi n mu ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC lasiko yii n kọ oun lominu, ati pe oun ko le duro ninu ẹgbẹ naa mọ, boun ba fẹẹ ki ipinnu oun lati di gomina ipinlẹ Ogun wa si imuṣẹ.
Nibẹ lo tun ti fẹsun kan Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun wi pe oun gan an lẹni to n da nnkan ru ninu ẹgbẹ APC, to si loun pẹlu rẹ ko le jọ wa ninu ẹgbẹ kan naa mọ, idi pataki to loun fi darapọmọ PDP.
"O yẹ ki ẹyin naa ti mọ pe Ọmọkri fẹran lati maa tako gbogbo awọn to ba n fẹ ilọsiwaju orileede yin. Alaaganna lo si maa n ṣe bẹẹ. Mi o fẹ da si ọrọ rẹ rara. Ti mo ba jẹ alamin ninu ẹgbẹ PDP, ṣe maa sọ ọ sita gbangba wi pe mo ti darapọ mọ wọn?
"To ba jẹ bi nnkan ṣe ri lo ṣe sọ yẹn, ṣe maa jade sita lati sọ pe mo fẹẹ dije du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP? Ko mọ nnkan to n sọ rara, ẹ si ma ṣe ka ọrọ rẹ kun rara.
No comments:
Post a Comment