Adajọ ni ki wọn fi ololufẹ meji ti wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ l’Abẹokuta pamọ s’ọgba ẹwọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 5, 2022

Adajọ ni ki wọn fi ololufẹ meji ti wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ l’Abẹokuta pamọ s’ọgba ẹwọn


Adajọ ile-ẹjọ giga t’ipinlẹ Ogun to wa lagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta ti paṣẹ pe ki wọn fi ọkọ at’iyawo kan ti wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ lagbegbe Lẹmẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun pamọ si ọgba ẹwọn to wa ni Ọba, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.

 
Ọjọbọ ti i ṣe Tọside, to kọja yii ni Onidajọ I. O. Abudu paṣẹ naa wi pe ki Kẹhinde Ọladimeji, ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Adejumọkẹ Raji, ẹni ọdun marundinlọgbọn lọ maa gbadun ara wọn, titi igbẹjọ miran yoo fi waye.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii ni aṣiri Kẹhinde ati Adejumọkẹ tu sita pẹlu ẹya ara oku ni ojule kejilelaadọrin, opopona MKO Abiọla, Lẹmẹ.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọ ara agbegbe Lẹmẹ yii ṣakiyesi ageku oku kan leti odo, ti wọn ko si mọ bo ṣe debẹ, eyi lo jẹ ki wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa agbegbe Kemta, Idi Aba, ti wọn si bẹrẹ iwadii lori ẹ.

Lẹyin ọsẹ meji la gbọ pe aṣiri awọn ọkọ at’iyawo yii tu pẹlu ẹya ara oku ti wọn gbe pamọ sinu ike omi nla ninu yara wọn. Lẹyin o rẹyin la gbọ pe Ifẹoluwa Adeh, ọmọ ọdun mejilelogun ni wọn tan lati pa danu.

ALARIYA OODUA gbọ pe adajọ ile-ẹjọ naa, Onidajọ I. O Abudu kọ lati gba ẹbẹ awọn t’ọkọ-t’iyawo naa nipa fifi oju aanu wo awọn, to si ni ki wọn lọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn.

Ṣaaju asiko yii ni agbẹjọro fawọn ọlọpaa, Oluwatosin Jacson ṣalaye fun ile-ẹjọ pe ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii lawọn mejeeji ṣe ẹṣẹ naa. O ni ṣe ni awọn mejeeji pawọpọ lati tan Ifẹoluwa Adeh, ẹni to jẹ ọrẹ timọtimọ si Adejumọkẹ wa sile wọn.

O nigba ti wọn tan Ifẹoluwa de ile wọn, wọn dana fun, wọn si fi oogun orun sinu ounjẹ naa, lẹyin eyi ni wọn dumbu ẹ, ti wọn si ta ori rẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun babalawo kan niluu Ibadan.

Ẹsun ti wọn ka si awọn mejeeji yii lẹsẹ la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran t’ipinlẹ Ogun, t’ọdun 2006, aba;a 324 ati 319(1).

Onidajọ Abudu wa sun igbẹjọ miran si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI