Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe wahala ati idaamu tuntun lo tun de ba olori ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tii ṣe Sunday Igboho lahamọ to wa lorileede olominira Bẹnin.
A gbọ pe ijọba orileede Bẹnin ti fi oṣu mẹfa kun asiko ti Sunday Igboho yoo lo lahamọ wọn to wa.
Oloye Yọmi Aliyu, agbẹjọro Igboho lo tu aṣiri yii sita wi pe awọn ti gba iwe ti wọn fi sun itimọle ọkunrin naa, eyi to lo kọ awọn lominu pupọ.
Sugbọn ṣa, ohun to n ya awọn eeyan lẹnu ni pe, ṣaaju asiko yii, Ọgbẹni Pẹlumi Ọlajẹngbesi, ẹni toun naa jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho toun filu Abuja ṣe ibugbe sọ pe ọkunrin naa ko ni pẹ ẹ jade lahamọ to wa laipẹ.
“Oloye Sunday Igboho yoo jade laipẹ, iro ayọ ati idunnu yoo si sọ kaakiri ilẹ Yoruba. Ko si iyemeji nibẹ pe akikanju ọkunrin gidi ni.
“Ọrọ to fidi mulẹ daadaa ni mo n sọ o, o kan jẹ pe awọn aṣaaju ilẹ Yoruba wa yii gbọdọ lọọ wa ọwọ iwa abosi, imọtara-ẹni-nikan, bọlẹ, ki wọn si gba ki iwa rere leke.”
Aliyu ninu ọrọ rẹ jẹ ko di mimọ pe ko si ẹsun kan ni pato ti wọn fi kan Igboho, eyi to ni ọwọ ti wọn fi mu ọrọ naa ko bojumu to, to si loun yoo lọ sile-ẹjọ ECOWAS lati tako bi wọn ṣe fẹẹ sun itimọle Igboho siwaju fun oṣu mẹfa miran.
Fun awọn to ba n ba iṣẹlẹ yii lọ, Igboho ti lo to ọjọ mẹrinlenigba, (204days) bayii.
No comments:
Post a Comment